Ọwọ tẹ Adebisi, tiṣa to n fi aṣọ ọlọpaa lu jibiti n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ayederu ọlọpaa kan, Adebisi Ayọdele, to n fi aṣọ agbofinro lu awọn eeyan ni jibiti ti ko ṣọwọ awọn ojulowo ọlọpaa n’Ibadan.

Ayọdele, to jẹ olukọ Ileewe alakọọbẹrẹ kan niluu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun, ni wọn lo maa n ṣe bii ọlọpaa kiri adugbo, ọna to si n gba ṣiṣẹ ọhun ni lati dara pọ mọ awọn onifayawo to n ti ẹyin odi ko ọja wọlu Ibadan lọna ti ko bofin mu.

 

 

Bi baba ẹni aadọta (50) ọdun yii ṣe n fi iṣẹ tiṣa boju niluu Abokuta, to n yọkun nidii iṣẹ oniṣẹ n’Ibadan, ree kọwọ awọn agbofinro too tẹ ẹ nitosi odo Aṣejirẹ, n’Ibadan, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun yii.

Nigba to n fidi iroyin yii mulẹ  lorukọ CP Adebọwale Williams ti i ṣe ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Alukoro wọn nipinlẹ naa, SP Adewale Ọṣifẹṣọ, ṣalaye pe ikọ to n da alaafia pada lagbegbe ti eto aabo ba ti mẹhẹ (Opereation Restore Peace) lo mu afurasi ọdaran naa pẹlu aọ agbofinro to wọ sọrun bii ẹni pe iṣẹ ọlọpaa lo n ṣe.

 

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Lọjọ Sannde lọwọ tẹ ọkunrin to maa n pera ẹ ni ASP Ayọdele yii, ṣugbọn ayederu ọlọpaa ni. Lasiko to n pese aabo ti ko bofin mu fawọn arinrinajo ti wọn jẹ onifayawọ pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ Mistubishi alawọ pupa, eyi ti  nmbar ẹ jẹ “ARP 34 AA”, ti wọn fi ko ọja naa ni wọn mu un.

“Iwadii ta a ṣe fidi ẹ mulẹ pe olukọ onipele kẹrinla lọkunrin yii jẹ nileewe aladaani kan to wa ni Ikereku-Ida,  niluu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun, ṣugbọn to n pera ẹ lagbofinro, to si n sọ fawọn eeyan pe oun ti gboye nla kan ti wọn n pe ni ASP nidii iṣẹ naa.

 

 

“O fẹnu ara ẹ jẹwọ pe aṣọ ọlọpaa kan to jẹ ti aladuugbo oun loun ji, ti oun fi n huwa ọdaran yii.”

Bakan naa lọwọ awọn agbofinro tẹ awọn afurasi ole mẹta kan ti wọn fipa gba ọkọ tirela nla kan to kun fun siga lọwọ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ siga kan n’Ibadan.

Nibi ti wọn ti n duro de ẹni ti yoo gba ọja na lọwọ wọn lawọn agbofinro ka wọn mọ, ti wọn si ko gbogbo wọn ti mọle.

Lọjọ kẹrindinlogun (16), oṣu yii, lọwọ tẹ awọn ni tiwọn laduugbo Too Geeti, Ibadan, lọna Eko.

 

 

Umaru Sunday ati Ito John gan-an la gbọ pe wọn ka mọ idi ẹru ole naa ko too di pe wọn pada ri Peju Ọkanlawọn mu nigboro Ibadan.

Ni kete ti iwadii ba ti pari lori ọran to sọ wọn dero atimọle lawọn mẹtẹẹta yoo foju ba ileẹjọ gẹgẹ bi
SP Ọṣifẹṣọ ṣe fidi ẹ mulẹ.

Leave a Reply