Ọwọ tẹ Afaa pẹlu ori eeyan tutu l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Afaa kan, Tunde Ọlayiwọla, lọwọ tẹ niluu Ondo, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, pẹlu ori eeyan tutu kan ti wọn ba nikaawọ rẹ.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Oyeyẹmi Oyediran, pe agbegbe kan ti wọn n pe ni Ajagbanlẹ, Ọka, niluu Ondo, lawọn ti ri ọkunrin ẹni aadọrin ọdun naa mu.

O ni ọwọ tẹ Afaa Ọlayiwọla lẹyin ti ẹnikan pe awọn ọlọpaa sori aago lọsan-an ọjọ naa lati ta wọn lolobo nipa ori eeyan tutu ti wọn fẹẹ waa gbe fun un.

Afaa ọmọ bibi ilu Oṣogbo, nipinlẹ Ọsun, ọhun lo ni o jẹwọ fawọn lasiko ti awọn n fọrọ wa a lẹnu wo pe ṣe loun fẹẹ fi ori eeyan naa ṣetutu ọla.

O ni afurasi ọdaran naa tun jẹwọ fawọn pe ẹgbẹrun lọna ọgọta Naira loun ra a bo tilẹ jẹ pe o  si kọ jalẹ lati darukọ ẹni to ta ọja ọhun fun un lasiko to fi n ba wa sọrọ.

Afaa ọhun lo ni awọn yoo foju rẹ bale-ẹjọ ni kete ti iwadii ba ti pari lori ẹsun ti wọn fi kan an.

 

 

 

 

 

Leave a Reply