Ọwọ tẹ awọn afeeyan-ṣetutu marun-un n’Ijẹbu, oku olokuu ni wọn n ku kiri

Faith Adebọla

Loootọ ni wọn n ṣadura pe ki oku sun ire lasiko ti eeyan ba ku, ṣugbọn awọn eeyan kan wa to jẹ iṣe tawọn yan laayo ni bi wọn ṣe maa ṣabẹwo si saare oku olokuu ti wọn ti sun, wọn aa hu oku naa, wọn aa yọ gbogbo ẹya-ara ti wọn nilo, ibaa jẹ oku ti wọn ti sin tipẹ.

Marun-un lara awọn afurasi ọdaran ti wọn n ṣiṣẹkiṣẹ yii lọwọ ba lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹta yii, nibi ti wọn ti n hu oku kiri ni wọn ka wọn mọ.

Orukọ awọn afurasi naa ni, Oluwaṣẹgun Oseni, oun lo dagba ju laarin wọn, ẹni ọdun mọkandinlaaadọrin ni (69), Osholẹ Fayẹmi, to tẹle e, ẹni ọgọta ọdun (60), Lawal Ọlaiya, ẹni aadọta ọdun (50), Oseni Adesanya, ẹni ọdun mọkandinlogoji (39), ati ẹni karun-un, tọjọ-ori ẹ kere ju, Ismaila Seidu, ẹni ọgbọn ọdun (30).

Ninu alaye ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, fi sọwọ s’Alaroye lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejila, oṣu Kẹta yii, lo ti sọ pe o ti pẹ tawọn eeyan ti n mu ẹsun wa pe awọn kọlọransi kan n ji oku olokuu hu, awọn si ti n dọdẹ awọn afurasi yii latigba naa.

Olobo kan lo ta awọn olọpaa ẹka Odoogbolu nipa awọn afurasi naa, eyi lo mu DPO teṣan naa, CSP Godwin Idehai, ko awọn eeyan rẹ sodi, wọn dọdẹ awọn afurasi naa lọ siluu Ọsọsa, wọn si ba wọn nibi ti wọn fi ṣe ibuba wọn niluu naa, wọn ba oriṣiiriṣii ẹya ara eeyan nikaawọ wọn, ṣinkun si ni wọn fi pampẹ ofin gbe wọn.

Nigba ti wọn ṣewadii wọn ni teṣan, awọn afurasi naa jẹwọ pe loootọ lawọn maa n lọọ hu oku olokuu kaakiri, wọn lawọn maa n gbẹ saare labẹnu ni, tawọn maa fi kan posi ti wọn fi sin oku labẹ ilẹ, ibẹ lawọn yoo ti mu awọn nnkan ẹya-ara oku tawọn fẹẹ mu, tawọn to sinku, ti wọn n wo saare oku wọn loke eepẹ ko ni i mọ pe oku ti di korofo labẹnu.

Wọn beere lọwọ awọn afurasi yii pe kin ni wọn n fi ẹya-ara oku ti wọn hu kiri ṣe, wọn ni tita lawọn n ta wọn, wọn lawọn ti ni awọn onibaara to maa n waa ra wọn, wọn lawọn ti wọn n lo wọn fi ṣe oogun owo, awọn ti wọn fi ẹya-ara ṣetutu ọla, ni wọn maa n waa ra a.

Ṣa, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Frank Mba, ti paṣẹ pe ki wọn taari awọn afurasi naa si ẹka to n tọpinpin iwa ọdaran abẹle lolu-ileeṣẹ ọlọpaa Ogun, l’Eleweẹran, Abẹokuta. O ni lẹyin iwadii ijinlẹ, ile-ẹjọ ni yoo gba awọn eleyii lalejo laipẹ.

Leave a Reply