Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọpọlọpọ awọn Fulani kan lọwọ tẹ pẹlu awọn ibọn agbelerọ nibi ti wọn ti n ṣe iwọde ‘June 12’ lọwọ niluu Akurẹ, lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja.
Ọna meji lawọn ọdọ ti wọn kopa ninu iwọde naa pin ara wọn si, Old Garrage, ni Ọba Adesida, lawọn kan ti bẹrẹ tiwọn, ti wọn si kọwọọrin lọ si agbegbe,’ A Difisan, NEPA ati Arakalẹ, nibi ti wọn ti n bawọn eeyan sọrọ lori idi ti wọn fi n ṣe iwọde.
Ọlọkọ, loju ọna marosẹ Ileṣa, Akurẹ si Ọwọ, lawọn isọri keji ko ara wọn jọ si, gbogbo ọkọ to ba n kọja ni wọn n da duro, ti wọn si n yẹ inu ati ara awọn ero ọkọ naa wo fínnífínní ki wọn too gba ki wọn kọja.
Eyi ni wọn n ṣe lọwọ ti ọkọ Họma bọọsi kan to jẹ ti ipinlẹ Gombe fi ba wọn lẹnu rẹ.
Wọn da ọkọ ti nọmba rẹ jẹ Gombe DKu 807 XA naa duro gẹgẹ bii iṣe wọn, ibi ti wọn ti n yẹ inu ọkọ yii wo ni wọn ti ri ọpọlọpọ ibọn agbelẹrọ to jẹ tawọn Fulani ọhun.
Kiakia ni wọn ti ranṣẹ pe awọn ẹsọ Amọtẹkun lati waa foju ara wọn ri ohun to n ṣẹlẹ, awọn Fulani ọhun atawọn nnkan ija to wa lọwọ wọn ni wọn kọkọ ko lọ si ọfiisi wọn ni Alagbaka ki wọn too pada waa wọ bọọsi to gbe wọn.
ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu ọkan ninu awọn to n ṣiṣẹ pọ pẹlu ẹṣọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo pe ipinlẹ Gombe lawọn tọwọ tẹ naa ti n bọ, ati pe ilu Eko ni wọn n lọ ki wọn too ko sọwọ awọn ọdọ to n ṣe iwọde l’Akurẹ.
Awọn tọwọ tẹ naa la gbọ pe wọn ṣi wa ni ikawọ awọn ẹsọ Amọtẹkun lasiko ta a n kọ iroyin yii lọwọ.