Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Diẹ lo ku ki wọn lu awọn gende meji kan pa lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, niluu Supare Akoko, nijọba ibilẹ Guusu Iwọ-Oorun Akoko, lẹyin tọwọ tẹ wọn níbi ti wọn n gbiyanju ati ji ọmọ ọlọmọ gbe.
ALAROYE gbọ pe ṣe lawọn afurasi ajọmọgbe mejeeji dibọn bii awọn to maa n ṣa aloku irin lagboole kan ti wọn n pe ni Ajakaye Sadiku Muraina, ni Supare.
Obinrin kan lati agboole ọhun lo deede fariwo ta, to si ke sawọn eeyan nigba to ri awọn afurasi naa lasiko ti wọn ku giri wọle wọn, ti wọn si n gbiyanju ati ji ọmọ rẹ gbe sinu apo nla kan ti wọn fa lọwọ.
Kiakia lawọn araalu ti su bo wọn, ti wọn si n lu wọn lalubami ki wọn too tun fa wọn le ọlọpaa ilu Supare lọwọ.