Ọwọ tẹ Christiana, ileeṣẹ ti wọn ti n ta ọmọ ìkókó lo da silẹ l’Agbado

Gbenga Amos, Ogun

 Akolo ọlọpaa ipinlẹ Ogun lobinrin kan, Christiana D’ivoire Iyama, ati ọmọbinrin kan, Margaret Ogwu, wa bayii. Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, to kọja yii lọwọ ba wọn nibi ti wọn ti n ṣe okoowo buruku kan. Niṣe ni wọn ko awọn ọmọbinrin jọ, ti wọn haaya ọkunrin lati fun wọn loyun bẹẹrẹbẹ, bawọn ọmọbinrin si ṣe n bimọ bii ẹlẹdẹ ni Christiana n ta awọn ẹjẹ ọrun naa fawọn kọsitọma ẹ ti wọn fẹẹ fọmọ ṣetutu ọla.

Olobo kan lo ta awọn ọlọpaa gẹgẹ bii alaye ti Alukoro wọn, SP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe, o lawọn ti wọn fura si iwa ọdaju to n waye nile kan to wa ni Ojule kẹrin, Opopona Ibrahim Famuyiwa, l’Agbado, ni wọn fi ọrọ naa to awọn agbofinro leti.

Loju-ẹsẹ ni SP Awoniyi Adekunle, DPO ẹka ileeṣe ọlọpaa to wa l’Agbado, atawọn ẹmẹwa ẹ ti lọ sile naa, tọwọ si ba awọn afurasi ọdaran meji yii. Wọn ni Christiana ni ọga agba to gba awọn ọmọbinrin naa siṣẹ, to n sanwo oṣu fun wọn, to si n haaya awọn ọkunrin oriṣiiriṣii lati maa ba wọn laṣepọ ki wọn le loyun, koun le maa ri awọn ọmọ ti wọn bi naa lu ta ni gbanjo fawọn ti wọn nilo ọmọọwọ lati fi i ṣe oogun owo.

Ninu iwadii wọn, Margaret jẹwọ pe ọmọ kan loun ṣi bi, o ni boun ṣe n rọbi lọwọ ni Christiana ti fa ọmọ naa yọ labẹ oun, to si gbe e lọ tẹjẹtẹjẹ, o lọọ ta a fun kọsitọma ẹ kan to ti n duro de e ni ẹgbẹrun lọna irinwo Naira (N400,000).

O tun ṣalaye pe ọga awọn yii ti ta ọmọ mẹta latọdọ awọn ọmọbinrin mi-in to fi n ṣowo ọmọ bibi ta ọhun.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, ti ni kawọn ọtẹlẹmuyẹ tubọ ṣiṣẹ iwadii to lọọrin lori iṣẹlẹ yii. Lẹyin iwadii lawọn afurasi ọdaran naa maa kawọ pọnyin rojọ niwaju adajọ.

Leave a Reply