Ọwọ tẹ Emmanuel nibi to ti n lu awọn oni-POS ni jibiti l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Ọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn kan, Emmanuel Okoroafor, ti dero ahamọ awọn ọlọpaa Eko, nibi to ti n fẹnu fẹra bii abẹbẹ niwaju awọn ọtẹlẹmuyẹ. Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọgbọnjọ, oṣu Disẹmba yii lọwọ palaba rẹ segi nibi to ti n fi kaadi ATM oriṣiiriṣii lu awọn ẹlẹrọ POS ni jibiti.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, lo sọrọ yii di mimọ loju opo ayelujara abẹyẹfo tuita (Twitter) rẹ.

Benjamin ni afurasi ọdaran yii gbọwọ ninu iwa gbaju-ẹ pẹlu  ọgbọnkọgbọn to maa n da. O ni boun ṣe maa n lu jibiti tiẹ ni pe o maa n sọ fawọn oni-POS pe ki wọn tẹ nọmba meje si ori ẹrọ wọn, gẹgẹ bii iye owo to fẹẹ gba, tabi ko ni ki wọn jẹ koun fọwọ ara oun tẹ ẹ si i. Fun apẹẹrẹ, to ba sọ pe oun fẹẹ gba ẹgbẹrun mejilelaaadọta Naira, iyẹn fifiti-tuu taosand Naira, Emmanuel yoo ni ki wọn tẹ nọmba N52,000:00, pẹlu odo meji saaye ti wọn maa n kọ kọbọ si.

Tawọn yẹn ba ti tẹ ẹ si, ti wọn si gbe ẹrọ POS le e lọwọ pe ko tẹ nọmba aṣiri rẹ, iyẹn pin-in-ni (PIN) rẹ si i, onijibiti yii yoo ti sare pa nọmba odo meji rẹ, ti owo naa yoo fi dinku si ẹgbẹrun marun-un ati igba Naira, (N5,200:00) yoo si tẹ pin-in-ni rẹ soju ẹrọ naa, pẹlu bọtinni OK, ko too da ẹrọ ọhun pada fun oni-POS.

Ohun ti eyi tumọ si ni pe dipo ti ẹrọ yii yoo fi yọ ẹgbẹrun mejilelaaadọta tọkunrin naa loun fẹẹ gba, ẹgbẹrun marun-un ati ọgọrun-un meji Naira pere ni ẹrọ naa yoo fa yọ ninu akaunti rẹ, ṣugbọn oni-POS ti ko ba fura, ẹgbẹrun mejilelaaadọta to ti kọkọ tẹ soju ẹrọ POS ọhun niyẹn yoo san fun un, laimọ pe jagunlabi ti dọgbọnkọgbọn si i.

Wọn ni gbara ti Emmanuel ba ti gbowo ati kaadi rẹ tan, niṣe ni yoo poora bii iso, nigba tawọn oni-POS ba si fi maa fura pe ina ti jo wọn, afurasi naa yoo ti di imi eegun tẹnikan ki i ri, ni yoo ba tun lọ sagbegbe tabi adugbo mi-in ti wọn ko ti i jagbọn buruku rẹ.

Hundeyin ni nigba tọwọ awọn agbofinro tẹ afurasi yii lagbegbe Ogudu si Ọjọta, nijọba ibilẹ Koṣọfẹ, lẹyin to lu oni-POS kan ni jibiti gẹgẹ bii iṣe rẹ, ṣugbọn tiyẹn pada yẹ risiiti ti ẹrọ itẹwo rẹ tẹ jade ko too ka owo le kọsitọma ọran yii lọwọ, lo ba figbe ta, lawọn eeyan to wa nitosi ba mu un silẹ de awọn ọlọpaa Rapid Response Squad (RRS) ti wọn mu un lọ sakolo wọn.

Wọn lafurasi naa jẹwọ pe ko ti i ju ọsẹ mẹta lọ toun bẹrẹ jibiti tuntun yii. Bakan naa lawọn oni-POS bii meji si mẹta jẹrii si i pe ọkunrin yii ti lu awọn ni jibiti pẹlu ọgbọn berebere rẹ ọhun.

Hundeyin ni nigba tawọn ṣayẹwo kaadi ATM ọwọ ẹ, pẹlu eyi to wa lakọọlẹ awọn oni-POS nibi ti wọn ti ṣe ‘gbaju-ẹ’ fun wọn, gẹlẹ ni nọmba kaadi naa ba tori ẹrọ mu, to fi han pe oun lẹni ti wọn n wa ọhun.

Wọn niwadii ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yii. Wọn lafurasi naa maa ba ile-ẹjọ lalejo laipẹ.

Leave a Reply