Ọwọ tẹ Ifẹdayọ nibi to ti fẹẹ ji ọmọ meji gbe l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọwọ ẹṣọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo ti tẹ ọkunrin ọlọkada kan, Ifẹdayọ Oluwadunsin, nibi to ti n gbiyanju ati ji awọn ọmọ iya kan naa meji gbe ninu ọkọ iya wọn, Abilekọ Kumuyi l’Akurẹ.

Ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ọhun l’ọwọ tẹ lagbegbe ileewe girama Aquinas, l’ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ẹgbẹ ọna ti Abilekọ Kumuyi paaki ọkọ rẹ si pẹlu awọn ọmọ mejeeji ninu rẹ lati sare ra nnkan nitosi ni afurasi ajọmọgbe ọhun ti rapala wọ inu ọkọ ti awọn ọmọ ọhun wa pẹlu erongba ati ji wọn gbe, ko le fi gbowo lọwọ obi wọn.

Afurasi ajọmọgbe ọhun ni wọn ti wọ lọ sile-ẹjọ Majisreeti kan to wa lagbegbe Oke-Ẹda, niluu Akurẹ, nibi ti wọn fi ẹsun jiji ọmọ gbe kan an.

Ẹsun yii ni agbẹjọro ijọba, O. F. Akeredolu, ni o ta ko abala kẹrin ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2010, eyi to lodi si iwa ijinigbe.

Akeredolu rọ ile-ẹjọ lati pasẹ fifi olujẹjọ pamọ sọgba ẹwọn titi di igba ti wọn yoo fi ri imọran gba lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.

Agbẹjọro olujẹjọ, Abilekọ O. Adedire, bẹbẹ fun sisun igbẹjọ siwaju ko le lanfaani ati fesi lori awọn ẹbẹ ti agbefọba fi siwaju ile-ẹjọ.

Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ, Onidaajọ D. S. Sekoni ni ki wọn ṣi fi afurasi ọhun pamọ sọdọ awọn ẹṣọ Amọtẹkun na. Ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹwaa ọdun ta a wa yii lo ni igbẹjọ yoo tun maa tẹsiwaju.

 

Leave a Reply