Gbenga Amos, Abẹokuta
Ọpọ eeyan lo mọ Paracetamol, ohun ti wọn si mọ to n jẹ bẹẹ ni oogun aparora ti wọn n lo. Ṣugbọn Paracetamol mi-in tun wa, ogbologboo ọmọ ẹgbẹ okunkun tawọn ọlọpaa ti n wa tipẹ ni, Rotimi Adebiyi lorukọ ẹ gan-an, ṣugbọn Paracetamol lawọn tiẹ mọ ọn si, wọn loun lo wa nidii ipaayan ati rogbodiyan awọn ẹgbẹ okunkun to n waye, paapaa lagbegbe Ifọ ati Abẹokuta, ṣugbọn ago ti de adiyẹ amookunṣika yii, o ti bọ sakolo ọlọpaa.
Gẹgẹ bii alaye ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe fun wa, o ni bawọn ọtẹlẹmuyẹ ṣe fimu finlẹ lori akọlu ati ija awọn ẹlẹgbẹ okunkun, eyi to waye leralera lẹnu aipẹ yii, lo jẹ ki wọn mọ pe Paracetamol ni ọdada to n dana ijangbọn ọhun silẹ, wọn loun lolori ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ, adugbo to wọnu kan lo n gbe niluu Ifọ, toun atawọn ẹmẹwa ẹ ba ti fẹẹ ṣoro bii agbọn lo maa n wa si Abẹokuta, ti yoo si tun yọ pọrọ pada siluu Ifọ to fi ṣe ibuba ẹ, ki ẹnikẹni too fura.
Lẹyin ti wọn ti n dọdẹ rẹ laimọ, ti olobo si ti ta awọn agbofinro pe jagunlabi ti wa nile, ọga ọlọpaa kan, CSP Ọlanrewaju Kalejaiye, ko ikọ ọlọpaa SWAT sodi, wọn si lọ siluu Ifọ lọganjọ oru, nnkan bii aago kan aabọ laajin oru ọjọ Abamẹta, Satide, ọgbọnjọ, oṣu Kẹrin yii, ni ọwọ tẹ Rotimi ṣinkun, ni wọn ba fi ṣẹkẹṣẹkẹ si i lọwọ, o di olu-ileeṣẹ ọlọpaa l’Eleweeran, l’Abẹokuta.
Lara awọn nnkan ija ti wọn ba lọwọ san’bẹ-sun-f’apo-rọ’ri ẹda yii ni ibọn ilewọ agbelẹrọ pompo kan, ọta ibọn ti wọn o ti i yin, oriṣiiriṣii oogun abẹnugọngọ, egboogi oloro ti wọn fura pe igbo ni yoo jẹ, ati ada kan.
CP Lanre Bankọle, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, ti paṣẹ ki wọn fi Paracetamol ṣọwọ sọdọ awọn ọtẹlẹmuyẹ to n gbogun ti ṣiṣe ẹgbẹkẹgbẹ nipinlẹ naa, ki wọn ṣewadii to lọọrin lori afurasi ọdaran yii.
O ni lẹyin eyi lawọn maa taari ẹ siwaju adajọ lati lọọ fimu kata ofin.