Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Diẹ lo ku ki wọn dana sun afurasi adigunjale kan, Tọpẹ Owolabi, tọwọ tẹ nibi to ti n fọ ile onile niluu Ondo laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja.
Ọkunrin ẹni ọgbọn ọdun ọhun ni wọn ba nibi to ti n jale ninu ile kan ti wọn n kọ lọwọ lagbegbe Elewuro, Sunbreaker, lọjọ naa.
Ẹni to nile ọhun, Oloye Justinah Ogunsusi Ọlabanji, ṣalaye pe oun ti n palẹmọ lati ko wa sinu ile naa loṣu to n bọ yii. O ni diẹ lara agbado ti wọn gbin sinu ọgba ile tuntun naa toun atawọn eeyan kan fẹẹ waa kore lo tu Tọpẹ lasiiri.
Mama yii ni lẹyin tawọn ya agbado tan loun sọ fun ọkan ninu awọn tawọn jọ lọ pe ko ṣilẹkun ki wọn le wo ibi ti wọn ba iṣẹ ile ọhun de.
Gbogbo igbiyanju wọn lati ri ilẹkun ṣi lo ja si pabo,
nitori ẹnikan wa ninu ile lọhun-un to ti tilẹkun lẹyin. Nibi ti wọn ti n pe wẹda ti wọn ra ilẹkun lọwọ rẹ lori aago ni ọkan ninu wọn ti kofiri afurasi naa lati oju ferese.
Lẹyin bii bii ọgbọn isẹju tí wọn ti n pariwo ni afurasi adigunjale yii too ṣilẹkun, lo ba doju ija nla kọ awọn gende mẹtẹẹta to tẹle mama oloye ọhun lọjọ naa.
Meji ninu wọn lo sa ladaa, to si tun ba awọn dukia mi-ín jẹ nibi to ti n wa gbogbo ọna lati sa mọ wọn lọwọ.
Pẹlu iranlọwọ awọn araadugbo ni wọn fi pada ri afurasi ọdaran yii mu. Bi wọn ṣe de e lokun tan lawọn ọdọ kan ti fẹẹ dana sun un, awọn agbaagba to wa nitosi ni wọn bẹ wọn, lẹyin eyi ni wọn ranṣẹ sawọn ọlọpaa to wa ni teṣan Yaba, niluu Ondo, lati waa gbe e.
Oriṣiiriṣii kọkọrọ ile, waya ina atawọn ohun eelo mi-ín ni wọn ba loke aja ti afurasi naa ko wọn pamọ si.
Afurasi ọdaran ọhun ṣalaye fun akọroyin wa pe ọmọ bibi ipinlẹ Ọsun loun, o ni iṣẹ kapẹnta loun n ṣe lagbegbe Ifẹ Garage, niluu Ondo. O ni ọrẹ oun kan to n jẹ Kunle lo gbe oun wa sinu ile naa, bawọn si ṣe wọle tan lo tilẹkun, to si pada lọ ni tirẹ.
Ọkan ninu awọn to wa nibi iṣẹlẹ yii ni Kunle wa lara awọn oṣiṣẹ to ba iya onile ọhun fa ina sinu ile rẹ, o ṣee ṣe ko jẹ asiko naa lo raaye rọ awọn ẹda kọkọrọ toun ati ọrẹ rẹ fi wọle laaarọ ọjọ naa lati ji awọn ẹru ẹlẹru ko.