Ọwọ ti ba Ramọta, obinrin to fi omi gbigbona pa ọkọ ẹ l’Abẹokuta

 Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ṣe ẹ ranti Ramọta Bello? Obinrin kan tawọn ẹbi ọkọ ẹ n wa lọsẹ diẹ sẹyin nitori omi gbigbona to da si ọkọ ẹ lara, to si sa lọ l’Abẹokuta. Ọwọ ofin ti to o bayii, o si ti wa lẹka ti wọn ti n gbọ ẹjọ awọn apaniyan.

Tẹ o  ba gbagbe, ọjọ kejila, oṣu Keji yii ni Ramọta gbe omi kana, to jẹ komi naa ho gidi, to si da a si ọkọ ẹ, Bello Salisu, ni gbogbo ara.  Wọn sare gbe ọkunrin naa lọ sọsibitu, ṣugbọn ọjọ keji lo dagbere faye.

Nigba ti Ramọta ti pitu buruku fọkọ rẹ tan lo ti sa lọ ni tiẹ, awọn eeyan ọkọ rẹ ti ọrọ si kan ko tete fi to ọlọpaa leti gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa Ogun ṣe wi. Ọjọ kọkanlelogun, oṣu Keji yii, ni wọn too fiṣẹlẹ aburu naa to teṣan ọlọpaa Lafẹnwa leti, tawọn ọlọpaa si bẹrẹ si i wa Ramọta, ti wọn si ri i mu nibi to sa lọ lọjọ kọkanlelogun, oṣu Keji, yii kan naa.

Ohun to fa ija to mu Ramọta, iya ọlọmọ meji to ti fẹ ọkọ ẹ latọdun kẹfa sẹyin, da omi gbigbona sọkọ ẹ  lara ko le rara.

Ọkọ rẹ lo pe awọn famili, iyẹn awọn aburo rẹ, pe ki wọn waa ba oun ba iyawo oun sọrọ, nitori o maa n febi pa oun atọmọ kan to n keu lọdọ oun.

Ọkunrin to ti doloogbe bayii sọ fawọn aburo ẹ nigba naa pe oun ti kilọ fun Ramọta titi pe ko yee mọ-ọn-mọ febi pa oun atọmọ to n keu lọdọ oun naa, o ni ṣugbọn iyawo oun ko yiwa pada, tinu rẹ lo n ṣe lọ.

Iyẹn lo ṣe ni kawọn aburo oun naa waa ba a sọrọ, boya yoo tiju wọn, ko si ni i fi ounjẹ da oun atọmọ naa lagara mọ.

Eyi lawọn aburo ọkọ rẹ meji da si, ti wọn bẹ Ramọta pe ko yiwa pada, nitori obinrin ire kan ki i febi pa ọkọ to fẹ ẹ sile, tabi ọmọ ọlọmọ to ba n gbe lọdọ wọn.

Ọjọ keji tawọn aburo ọkọ da sọrọ yii ni Ramọta to bori dẹdẹ yii gbe omi kana lọwọ aarọ, tawọn araale tiẹ ro pe o fẹ ro amala fọkọ rẹ ni, abi ko jẹ pe o fẹẹ pogi, nitori wọn ni omi naa ho daadaa, ko si tete sọ ọ kalẹ.

Afi bo ṣe sọ omi ọhun kalẹ tan to yi i le ọkọ rẹ lori, ti gbogbo ara iyẹn si bo tooroto, to waa jade laye lọjọ keji ti iyawo rẹ bo o bii pe ṣàkì ẹran ni.

Ṣaa, ọwọ ọlọpaa ti ba iyawo to pa ọkọ rẹ yii, o si ti wa lọdọ awọn ti wọn n ri si ẹsun apaayan.

 

Leave a Reply