Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti pada tẹ Emmanuel Akpan, ọmọ ọdọ to dumbu ọga rẹ, Abilekọ Fẹbiṣọla Caroline Adedayọ, bii ẹran l’Ondo, to si tun ji awọn nnkan ini rẹ ko sa lọ.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, Akpan to wa lati ipinlẹ Akwa-Ibom lọwọ tẹ niluu Abẹokuta, lẹyin bii ọsẹ mẹta ti wọn ti n wa a.
Nigba ti akọroyin wa n fọrọ wa ọmọkunrin ẹni ogun ọdun ọhun lẹnu wo, alaye to ṣe fun wa ni pe, oun ati ẹni kan tórúkọ rẹ ń jẹ Goodness lawọn jọ gbimọ-pọ da ẹmi iya agbalagba naa legbodo.
O ni lati ọdun 2014 loun ti n ṣiṣẹ ọmọ ọdọ niluu Ondo, nnkan bii osu kan sẹyin lo ni Goodness waa ba oun, to si ni oun fẹ ki oun lọọ ba ọga tí òun ṣẹṣẹ kuro lọdọ rẹ ṣiṣẹ ki wọn le raaye pa a, ki wọn si ko owo rẹ sa lọ.
Odidi ọdun bii mẹrin ni Goodness fi ṣiṣẹ pọ pẹlu obinrin ti wọn n pe ni Iya Kẹmi olounjẹ naa ko too finnu findọ kuro ninu oṣu kejila, ọdun to kọja, pe oun fẹẹ lọọ kọṣẹ ọwọ.
Akpan ni ọjọ karun-un ti oun bẹrẹ iṣẹ ni Goodness funra rẹ waa ba oloogbe ọhun nile rẹ to wa lagbegbe Ifọkanbalẹ, Sabo, niluu Ondo, ti wọn si jọ sọrọ daadaa ki awọn mejeeji too lọ si ṣọọbu ọga wọn to wa ni Lipakala, loju ọna marosẹ Ondo si Ọrẹ, nibi tawọn mejeeji ti fohun ṣọkan lati pa obinrin naa laarin alẹ ọjọ Aiku, Sannde, si ọjọ Aje, Mọnde.
O ni laarin oru loun lọọ ba Iya Kẹmi nibi to sun si ninu palọ rẹ, ti oun si fi ada dumbu rẹ bii ẹran.
Ni kete to pa obinrin ọhun tan lo ni oun ti sare pe Goodness, ṣugbọn ti nọmba rẹ ko lọ mọ.
O ni ero awọn ni pe owo wa lọwọ obinrin naa daadaa, idi tawọn si fi pinnu lati pa a niyi, ki awọn le ri owo rẹ jì ko sa lọ.
Akpan ni iyalẹnu lo jẹ foun nikẹyin nigba ti oun pa iya naa tan ti oun ko si ri ju ẹgbẹrun mẹta aabọ naira pere ji ko ni gbogbo ile rẹ.
O ni airi owo pupọ ji ko lo bi oun ninu ti oun fi ji awọn nnkan ẹṣọ olowo iyebíye ati jẹnẹreto kan gbe.
Bo tilẹ jẹ pe Goodness to ni ṣe lawọn jọ gbimọ-pọ pa iya oniyaa ṣi n ṣẹ pe irọ lo fi iṣẹlẹ naa pa mọ oun, síbẹ̀ Kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Bọlaji Salami, ti ni awọn mejeeji ni wọn yoo foju bale-ẹjọ lati lọọ sọ tẹnu wọn.