Florence Babaṣọla
Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti sọ lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lori wahala bi awọn agbebọn ṣe pa eeyan mẹfa ninu mọlẹbi kan ṣoṣo ni Gaa Fulani to wa niluu Waasinmi, nipinlẹ Ọṣun.
Alaga igbimọ tijọba gbe kalẹ lori ọrọ ibagbepọ alaafia laarin awọn Fulani/Bororo pẹlu awọn agbẹ oninnkan-ọsin, Mudaṣiru Toogun, lo sọrọ naa fawọn oniroyin laipẹ yii.
O ni aṣeyọri nla lọrọ ẹni kan ti ọwọ tẹ naa ati pe o ti wa lakolo awọn ọlọpaa, nibi to ti n ran wọn lọwọ lati sọ ohun to mọ nipa iṣẹlẹ naa.
Mojumọ ọjọ kẹrinla, oṣu yii, lawọn agbebọn ọhun pa Alhaji Momodu Yaya, ẹni ti inagijẹ rẹ n jẹ Samu, wọn pa iyawo rẹ meji; Adamọ ati Awawu, bẹẹ ni wọn pa mẹta lara awọn ọmọ-ọmọ rẹ; Ibrahim, Abdullahi ati Moriamo.
Toogun ṣalaye pe wọn ti sinku awọn mẹfẹẹfa naa niluu Ilọrin nilana ẹsin Islam. O ni ẹni to ṣoju Emir tilu Ilọrin nibi isinku naa gboṣuba fun ọgbọn-inu tijọba ipinlẹ Ọṣun lo lati fi mu ọrọ naa lẹyin ti awọn aṣoju ijọba Ọṣun sọ fun wọn pe iṣẹlẹ naa ki i ṣe ọrọ ẹlẹyamẹya rara.
O ni itẹ-oku awọn Musulumi niluu Ilọrin, ni wọn sin awọn ọmọ mẹtẹẹta si, nigba ti wọn sin baba naa atawọn iyawo rẹ sẹyin mọṣalaaṣi kan ti baba naa kọ sinu ọgba ile-nla to ni siluu Ilọrin.
Toogun fi kun ọrọ rẹ pe ọmọ kan to tun fara pa lasiko iṣẹlẹ naa ti n gbatọju, ijọba si ti ṣeleri iranlọwọ to peye fun un.
Nigba to n sọrọ lori ohun ti Toogun sọ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe loootọ ni aṣeyọri ti n wa lori ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa, ṣugbọn ko sọ boya awọn ri ẹnikan mu tabi bẹẹ kọ.