Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ileeṣẹ ọlọpaa ti mu idile Okpara ti wọn wa lati ipinlẹ Delta, ṣugbọn ti wọn n gbe ni Ṣagamu. Wọn ni iṣẹ ajinigbe ni gbogbo wọn n ṣe jẹun.
Ijinigbe to pọ ju ni Ṣagamu ati agbegbe ẹ lọdun 2020 to kọja yii, lo fa a ti Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, CP Edward Ajogun, ṣe paṣẹ pe ki wọn wa awọn to wa nidii ibajẹ naa jade.
Nigba ti DPO ẹkun Ṣagamu atawọn eeyan rẹ yoo si pari iwadii abẹnu wọn, baba kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Oweniwe Okpara, pẹlu awọn ọmọ ẹ mẹta ti orukọ wọn n jẹ Samson Okpara, Bright Okpara ati Eze Okpara, ni wọn ri mu gẹgẹ bii ikọ ajiiyangbe to n da Ṣagamu laamu.
Ọwọ ọlọpaa tun ba Christian Ishaha, wọn loun lo fun wọn nile ti wọn n gbe.
Agbegbe Ajaka ni wọn ti mu wọn ni Ṣagamu, awọn ọlọpaa sọ pe eeyan mẹjọ ti wọn ti ji gbe lawọn agbegbe kaakiri lawọn tori ẹ mu wọn.
Gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa Ogun, ṣe wi, o ni nibi itẹsiwaju iwadii ni wọn ti ri i pe awọn mẹta kan tun ṣi ku ti wọn jẹ ọmọ Okpara yii, to jẹ ijinigbe naa ni wọn fi n ṣe iṣẹ oojọ wọn.
Awọn mẹta naa ni Godwin Okpara, Godspower Okpara ati Matthew Okpara. Awọn mẹta yii ni wọn maa n dira ogun, ti wọn yoo lọọ ji eeyan gbe wa, nigba ti Samson, Bright ati Eze maa n ṣọ irin awọn ti wọn ba fẹẹ ji gbe titi ti ọwọ yoo fi ba wọn.
Bakan naa ni ọkunrin, Emmanuel Joseph, wa ninu awọn ikọ to n ji awọn eeyan gbe yii. Owo nla ti awọn Okpara maa n fi ojoojumọ ka, ti Emmanuel maa n ri wọn, lo tori ẹ beere pe nibo ni wọn ti n rowo, nigba to si jẹ pe famili wọn loun naa, wọn jẹwọ fun un, wọn si mu un wọnu ẹgbẹ ajinigbe, ni wọn ba jọ n ṣiṣẹ laabi lọ.
Nigba tọwọ yoo ba wọn ṣa, wọn mu baba atawọn ọmọ ẹ mẹta ni Ajaka, Ṣagamu. Awọn mẹta yooku ti i ṣe Godwin, Godspower ati Matthew Okpara, sa lọ si Delta, nigba ti wọn gbọ pe wọn ti mu baba awọn pẹlu awọn aburo awọn. Ṣugbọn ikọ ọlọpaa Delta to ti gbọ nipa wọn tẹlẹ nawọ gan wọn lọwọ kan ni.
Ibi ti wọn maa n tọju awọn ti wọn ba ji pamọ si ni awọn ọlọpaa lọọ wo lulẹ n’Ijẹbu-Ayepe lẹyin tọwọ ba wọn. Iṣe oko ni Oweniwe n ṣe nibẹ tẹlẹ ko too sọ ibẹ di ibi ti wọn n tọju awọn ti wọn ba ji gbe si, ti wọn yoo si ni kawọn ẹbi wọn lọọ mu owo nla wa bi wọn ba fẹẹ ri wọn gba lalaafia ara.
Diẹ ninu awọn nnkan tawọn ọlọpaa sọ pe awọn ba nibuba wọn naa ni ọta ibọn mẹta ti wọn ti yin, gaasi idana, tapoli ti wọn fi n bo nnkan mọlẹ, awọn nnkan idana nile ounjẹ, baagi awọn obinrin ati owu ti wọn fi n hun nnkan.
Awọn ti wọn ti ji gbe ri gẹgẹ bawọn ọlọpaa ṣe sọ ni: Okechukwu Onwubiko ti wọn ji gbe lọjọ kẹrin, oṣu keji, ọdun 2020. Abilekọ Areoye Olufunkẹ ti wọn ji gbe lọjọ kẹta, oṣu kọkanla, ọdun 2020, Abilekọ Adijat Adelẹyẹ; ọjọ kọkanla, oṣu kọkanla, ọdun 2020, ni wọn ji oun gbe. Ashaye Ọlayinka Tobi, wọn gbe oun lọjọ kejila, oṣu kọkanla, ọdun 2020.
CP Edward Ajogun, gboriyin fawọn ọlọpaa to hu mọlẹbi ajinigbe yii jade, o si rọ awọn araalu lati maa fọwọsowọpọ pẹlu ọlọpaa nipa tita wọn lolobo bi wọn ba kofiri awọn ẹni ibi bii eyi.