Ọrẹoluwa Adedeji
Ọṣẹ ti ọwọngogo Naira to wa nita latari bi ijọba ṣe paarọ owo ti a n na tẹlẹ, ti wọn ko si ko owo tuntun to to jade ko kere rara. Ọwọn owo naa ti sọ mọlẹbi kan sinu ibanujẹ pẹlu bi dokita ṣe kọ lati tọju iyawo ile kan to loyun sinu nitori ọkọ rẹ ko ri owo ti dokita ni ko san mu silẹ, awọn ọlọsibitu ọlọsibitu ko si fẹẹ ṣiṣẹ ọfẹ. Aitete ri owo gba ni banki naa lo ṣeku pa obinrin alaboyun naa to wa lati agbegbe Kasuwan Magani, nijọba ibilẹ Kajuru, nipinlẹ Kaduna.
Ọkọ obinrin ọhun, James Auta, ṣalaye pe nigba ti oun gbe iyawo oun lọ si ileewosan, dokita ni oun gbọdọ san awọn owo kan silẹ ki oun too le ṣe ayẹwo si iyawo oun. Eyi lo mu oun sare gba ibi maṣinni ATM lati gba owo, ṣugbọn oun ko rowo gba.
James ni, ‘‘Mo sare lọ si banki mi lati lọọ gba owo, ṣugbọn n ko rowo gba nibẹ. Mo tun lọ sọdọ awọn oni POS, awọn naa ko ri owo fun mi. Latigba tọrọ owo tuntun yii ti ṣẹlẹ lọpọlọpọ awọn oni POS ti kogba sile, ti wọn ti tilẹkun ṣọọbu wọn. Nitori pe n ko ri owo gba, ti awọn ọlọsibitu ko si gba lati tọju rẹ ni mo fi ni ko jẹ ka maa pada lọ sile pẹlu igbagbọ pe Ọlọrun yoo sọ ọ layọ.
Lati nnkan bii aago mọkanla alẹ ni iyawo mi ti bẹrẹ si i rọbi, ni mo ba pe ọkan ninu awọn nọọsi adugbo pe ko waa ba mi mojuto o niwọn igba ti wọn ko ti da wa lohun lọsibitu nitori owo ti a ko ri san. Loootọ ni iyawo mi bimọ, ṣugbọn bo ṣe bimọ tan ni ẹjẹ n da lara rẹ ti ẹjẹ naa ko si duro rara. Gbogbo akitiyan nọọsi yii lati da ọwọn ẹjẹ naa duro lo ja si pabo, bẹẹ ni iyawo mi jade laye’’. Bayii ni ọkunrin naa sọ pẹlu ibanujẹ.
Ọpọlọpọ araalu ni airi owo tuntun yii gba ti ṣakoba fun, ounjẹ ko ṣee ra, awọn to fẹẹ jade tabi rin irinajo ko ribi lọ, awọn tara wọn ko ya ti wọn fẹẹ roogun ko rowo wọn ti wọn ko si banki gba lati ra ohun ti wọn fẹ, ohun gbogbo si di rudurudu.