Oyetọla ṣebura fun awọn alaga ijọba ibilẹ tuntun l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹwaa, 2022, ni Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Adegboyega Oyetọla, ṣebura fun awọn alaga ijọba ibilẹ, ọfiisi idagbasoke agbegbe ati awọn eeria kansu, ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan ni ọjọ Abamẹta,Satide, ọsẹ to kọja yii.

Ni ọfiisi gomina to wa l’Abere, ni eto naa ti waye. Nibẹ ni Oyetọla ti ke si awọn alaga mọkandinlaaadọrun-un naa lati pese iṣejọba to kunju oṣunwọn fun awọn araalu.

Gomina ṣalaye pe idibo naa, eyi to waye lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, yẹ ko ti waye tipẹ, ṣugbọn oniruuru nnkan tijọba ko fọkan si bii ajakalẹ arun Korona, wahala Endsars ati bẹẹ bẹẹ lọ, lo da a duro.

Bakan naa lo ni bo ṣe gba awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun ni ọpọ asiko lati tun ofin eto ijọba ibilẹ ṣe lati dibo fun kanselọ, ti wọn yoo yan alaga laarin ara wọn ati didibo fun alaga lọtọ, tun wa lara awọn nnkan to fa ifasẹyin naa.

O ni inu oun dun bayii pe ijọba ipinlẹ Ọṣun ti bọ soju ọna ilana to tọ ninu idibo ijọba ibilẹ, eyi ti wọn lo lasiko idibo naa nipa didibo fun alaga lọtọ, ti wọn si dibo fun awọn kansẹlọ naa lọtọ.

Gomina dupẹ lọwọ awọn araalu fun ifọwọsowọpọ wọn lasiko idibo naa, o si fi da wọn loju pe wọn ko ni i kabaamọ lori awọn eeyan ti wọn gbe sipo naa.

Oyetọla ke si awọn ti wọn jawe olubori lati ma ṣe ri ẹnikẹni bii ọta, ki wọn tete gbe igbesẹ lati wa ọna alaafia pẹlu awọn ti wọn jọ dupoo naa.

O tun rọ wọn lati mọ pe ohun ti awọn araalu n reti latọdọ wọn pọ pupọ, ki wọn tete bẹrẹ iṣẹ idagbasoke agbegbe wọn kiakia, nitori itan ko ni i gbagbe ohunkohun ti wọn ba ṣe.

O ni wọn ko gbọdọ da gbe igbesẹ gẹgẹ bii ifẹ inu ara wọn, ki wọn ri i pe awọn nnkan tawọn araalu n fẹ ni wọn n ṣe.

Leave a Reply