Oyetọla ṣepade pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ APC l’Ọṣun, o ni fungba diẹ ni ifasẹyin to de ba awọn

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Lẹyin to fidi-rẹmi nibi eto idibo gomina to waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun yii, Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Adegboyega Oyetọla, ti sọ pe fungba diẹ ni ifasẹyin ti ẹgbẹ oṣelu APC ri ninu idibo gomina to waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun yii.

Nibi ipade kan to waye nile ijọba ni Oke-Fia, niluu Oṣogbo, ti ogunlọgọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa ti kopa, ni Oyetọla ti sọ pe adanwo lati ọdọ Ọlọrun ni ọrọ ijakulẹ ninu ibo naa jẹ.

O ke si awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa lati pada si wọọdu wọn, ki wọn bẹrẹ iṣẹ ẹgbẹ wọn pada bi wọn ṣe maa n ṣe e, ki wọn ma si ṣe jẹ ki ifasẹyin ranpẹ yii di oju wọn si iṣẹ nla to wa niwaju.

Oyetọla ni, “Ahesọ ti n lọ kaakiri pe mo sa kuro nipinlẹ Ọṣun ni kete ti wọn kede esi idibo naa. Bẹẹ la gbọ ti awọn PDP n sọ pe mo fẹẹ sọ dukia ijọba di temi. Ẹ ma da wọn lohun, wọn kan n janu lasan ni.

“Mo pe gbogbo yin sibi lati jẹ ki ẹ mọ pe fungba diẹ ni ijakulẹ ti a ni yii. Adanwo lati ọdọ Ọlọrun lati mọ ipinnu wa nipa rẹ ni, a si maa tẹsiwaju. Iṣẹ Ọlọrun ni wa, a ko ni i bẹru.

“Ẹ pada si ileedibo ati wọọdu yin lati bẹrẹ iṣẹ ẹgbẹ gẹgẹ bo ṣe wa tẹlẹ, ẹ maa ṣepade yin loorekoore. Iṣẹ nla lo wa niwaju wa, a ko si gbọdọ faaye gbe ifasẹyin ranpẹ yii lati da wa duro”.

Gomina Oyetọla fi kun ọrọ rẹ pe ijọba ti ba awọn oṣiṣẹ alaabo sọrọ lati ri i pe aabo to daju wa fun ẹmi ati dukia awọn araalu, bẹẹ lo sọ pe gbigbe lalaafia ṣe pataki.

“Awọn kan ti n lọ kaakiri lati di awọn araalu lọwọ lẹnu iṣẹ wọn. Ẹ ma ṣe jẹ ki ọkan yin daamu. Mo ti ke si awọn ẹṣọ alaabo lati ri i pe aabo to peye wa. A gbọdọ tẹ siwaju lati jẹ ipinlẹ alaafia, a ko ni i faaye gba ẹnikẹni lati ṣiwa-hu.”

Leave a Reply