Jide Alabi
Iroyin ayọ to de fun awọn eeyan ipinle Ọṣun ni ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, ni bi gomina ipinle naa, Adegboyega Oyetọla, ṣe fọwọ si sisan owo-oṣu tuntun fawọn oṣiṣẹ to kere ju lọ ti ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ti n beere fun lati ọjọ yii. Bẹẹ lo ni lati akoko yii lọ, awọn oṣiṣẹ to ba yẹ fun igbega yoo maa gba a pẹlu bo ṣe gbẹsẹ kuro lori ofin to de igbega awọn oṣiṣẹ.
Oyetọla ni sisan owo-oṣu tuntun yii yoo bere lati ọjọ kin-in-ni, oṣu kọkanla, ọdun yii. Gomina ni eyi jẹ abọ abajade igbimọ ijọba ati egbẹ oṣiṣẹ ti awọn gbe kalẹ lati ṣiṣẹ lori bi ọrọ igbaye-gbadun awọn oṣisẹ yoo ṣe jẹ yiyanju.
Bẹẹ lo dupẹ lọwọ ẹgbẹ oṣiṣẹ nipinle Ọṣun fun ifarada wọn, ṣiṣẹ takuntakun ati ifẹ ipinlẹ naa to mumu lookan aya wọn.
Oyetọla rọ awọn oṣisẹ lati fi ẹmi imoore wọn lori ohun ti ijọba ṣe yii nipa titubọọ tẹpa mọṣẹ daadaa si i.