Oyetọla dupẹ pe Tinubu wọle aarẹ, o loun naa maa pada sipo gomina laipẹ

Faith Adebọla

Yooba bọ, wọn lọrọ to ba da ni loju ki i kọsẹ lete, gomina ipinlẹ Ọṣun ana, ti wọn fibo rọ loye lọdun to kọja, Adegboyega Oyetọla, ti sọ pe oun ko fọrọ sabẹ ahọn sọ o, tori ohun to da oun loju gbangba ni, o loun maa pada sipo gomina ipinlẹ naa laipẹ lai jinna.

Oyetọla sọrọ idaniloju yii lasiko to n dupẹ lọwọ awọn alatilẹyin rẹ, awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC),  nipinlẹ Ọṣun, atawọn mọlẹbi rẹ ti wọn waa fijokoo pọn ọn le fun ti ayẹyẹ iranti ọdun kejila ati adura akanṣe fun mama rẹ, Oloogbe Alaaja Wulemọtu Oyetọla.

Ilu abinibi rẹ, Iragbiji, nijọba ibilẹ Boripe, nipinlẹ Ọṣun, layẹyẹ naa ti waye lopin ọsẹ to kọja.

Amọ ninu ọrọ imọriri ṣoki kan to sọ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹta yii, Adegboyega Isiaka Oyetọla sọ pe:

“Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun Ọba fun awọn iṣẹ iyanu rẹ laye wa. A dupẹ lọwọ Ẹ pe o fun Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu laṣeyọri, a si dupẹ, a tọpẹ da, lọwọ awọn eeyan wa ti wọn ṣatilẹyin fun un, ti wọn duro ti i.

“A fẹ ki gbogbo yin mọ pe ẹgbẹ oṣelu APC nikan lo le fun wa ni aṣeyọri. Ọlọrun lo gbe ẹgbẹ yii kalẹ fun wa. Ibẹ nikan ni oore ati anfaani wa. Ẹ dakun, ẹ dibo fun APC nibi gbogbo. To ba jẹ loootọ la fẹẹ jẹ mukundun ijọba apapọ, ẹ jọọ, ẹ dibo fawọn ọmọleegbimọ aṣofin, awọn tẹ ẹ ba yan ni wọn maa ṣiṣẹ pẹlu wa nigba ta a ba pada sori aleefa, tori o daju pe a maa pada sipo wa laipẹ.

“A o gbagbọ ninu nnkan mi-in lẹyin adura o. Ohun tawa gbọnju mọ niyẹn. Ẹ ṣaa jẹ ka maa gbadura, ka le lẹnu ọpẹ s’Ọlọrun nigbẹyin.” Gẹgẹ bo ṣe wi.

Ẹ oo ranti pe Ademọla Adeleke ni wọn kede pe o jawe olubori ninu ibo sipo gomina to waye nipinlẹ Ọṣun lọdun to kọja, to si fẹyin Oyetọla atawọn oludije yooku janlẹ. Lati oṣu Kọkanla, ọdun naa, ni wọn ti bura fun un, to si ti n ṣakoso. Amọ laipẹ yii ni igbimọ igbẹjọ to n gbọ awuyewuye to su yọ ninu ibo pari igbẹjọ wọn, ti wọn si gbe idajọ kalẹ pe Oyetọla lo yẹ ko wa nipo, wọn loun ni ibo rẹ tẹwọn ju, nigba ti wọn ṣatunṣe sawọn magomago kan ti wọn lo waye lawọn agbegbe idibo kan.

Amọ lẹyẹ-o-sọka ni Adeleke ti pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun, ibẹ si lẹjọ naa de duro titi dasiko yii.

Leave a Reply