Oyin tu ipolongo ibo APC ka ni Kogi

Monisọla Saka

Awọn oyin ti ko sẹni to mọ ibi ti wọn ti tu wa ni wọn doju iwọde ati ipolongo ibo awọn ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Kogi bolẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ karun-un, oṣu Kọkanla, ọdun yii. Lagbegbe Ihima, Okene, nipinlẹ ọhun, ni wọn ti ni iwọde naa waye nigboro ilu naa, lati le polongo fun gbogbo awọn oludije dupo lẹgbẹ naa.

Gẹgẹ bi ọkan ninu awọn ti wọn n ṣe ipolongo ibo naa ṣe ṣalaye fun akọroyin Saharareporters, o ni, “Jẹẹjẹ wa la n rin laarin igboro ilu Okene fun ipolongo awọn ọmọ ẹgbẹ wa, lojiji lawọn oyin ya wọ aarin wa, wọn n le awọn eeyan wa kiri, wọn si ṣe bẹẹ da ipolongo ibo wa ta a n ṣe ru”.

Ilu ti wọn ti ṣe ipopongo yii ni Natasha Hadiza Akpoti Uduaghan, to jẹ oludije dupo Sẹnetọ fun Aarin Gbungbun ipinlẹ Kogi ti wọn ti lọọ ṣe ipolongo yii ti wa. Lọdun 2019, obinrin ọhun lo gbapoti ibo gomina lorukọ ẹgbẹ SDP, toun ati Yahya Bello si jọ ta kanngbọn dupo naa. Ṣugbọn inu ẹgbẹ oṣelu PDP lo wa bayii.

Yahya Bello to jẹ gomina nipinlẹ ọhun ni wọn lo ti kọkọ jade sita sọrọ ri pe gbogbo ọna loun maa fi ri i daju pe gbogbo awọn oludije dupo labẹ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ naa lo wọle, bẹẹ lo dunkooko mọ awọn ẹgbẹ alatako pe oun maa fi oju wọn ri mabo nitori ọrọ ibo ọhun.

Ṣaaju akoko yii ni gomina ọhun ti ti ile ẹgbẹ awọn PDP nipinlẹ naa pa, lojuna ati le gba ẹgbẹ alatako mọlẹ.

Bo tilẹ jẹ pe nnkan o ṣẹnuure laarin APC atẹgbẹ alatako nipinlẹ naa, ko sẹni to le sọ pato ibi tawọn oyin ti ya wa, boya boya boya ni wọn n sọ.

Leave a Reply