Oyinbo muti, ọti n pa kuku

Ọlọrun ma jẹ ki wọn mu baba yin lọ. Emi kuku ti kilọ fun un, Ọlọrun ma jẹ ki wọn gbe e lọ. Awọn ti wọn ṣofin korona ni o, nitori gbogbo wa ni wọn kilọ fun pe kinni naa ti tun n ṣe awọn eeyan, pe ki gbogbo eeyan maa lo ibomu, nigba ti Ọlọrun si ṣe e ti kinni naa ko mu ẹnikankan ni sakaani tiwa, kawa naa maa ṣọra ni. Ohun ti emi si n ṣe niyẹn, lati ọjọ yii, koda awọn kan wa ti wọn tori ẹ pe mi lara oko, emi si ti fara mọ ọn, ṣugbọn awọn to ri mi mọ pe emi o le ṣe ki n ma lo o, bẹẹ ni n ko si ni i lọ si pati kan, ko sode ariya lọrọ mi.

Ṣugbọn Alaaji ki i gbọran, ki i gbọran rara, bo ba si fẹẹ ṣe nnkan ti ẹ ba ni ko ma ṣe e bayii, eegun rẹ yoo tubọ maa le si i ni, agaga bo ba ti jẹ nnkan to ni i ṣe pẹlu ọrọ ode ati ariya bayii. Bo ba ti waa jẹ nnkan to ni i ṣe pẹlu oun ati Aunti Sikira ni, ọrọ pari niyẹn. Ohun to si ṣẹlẹ nile wa niyẹn lọjọ Alamisi, ọjọ ikomọ Sẹki. Iya ọlọmọ ti loun o ṣe pati, o ni gbogbo eyi to wa nita yii, beeyan ba ni ki oun maa ṣe inawo tabi pati kan, wahala ni tọhun kan maa ko ara ẹ si lasan. O ni bawọn ti wọn ba waa sọmọ lorukọ ba ti ṣetan, tawọn si wa nnkan jijẹ fun wọn, o ti pari niyẹn.

Emi naa fara mọyẹn daadaa. Ọkọ ẹ naa ti gba fun un, o ni ohun tiyawo oun ba ṣe loun fara mọ, nigba to si ti waa ba mi ti mo ti ni ko si ohun to dun to o, pe bo ṣe wi yẹn ni ka ṣe e, ọkan wa ti balẹ pe ko si wahala kan. Aarọ la ti ji lọ sile wọn, ti a si ti se ọpọlọpọ irẹsi, awọn araale ati awọn araadugbo nikan la se e fun, a si tun ṣe teeki-ewe fawọn ti wọn ba fẹẹ gbe e lọ, iyẹn awọn to fẹẹ sọmọ lorukọ. Nigba ti wọn si de ti a ti ṣeto isọmọlorukọ tan, kaluku gbe ounjẹ ẹ dani ni, ko si pe wọn n duro mọ, wọn kan n lọ si ọna ile wọn ni.

Inu awọn ti wọn wa sọmọ lorukọ dun de gongo, nitori mo kan gbe odidi owo fun wọn ni, ko ma di pe wọn n tọrọ owo tabi ki wọn maa fi ọgbọn sọ pe owo kan lawọn n wa. Awa mẹrin pere naa la jẹ obinrin ta a wa lati ile, emi ati Safu lati kọkọ ji lọ, Iya Dele ati iya mi waa ba wa nibẹ, mo ni ki wọn lọọ fi mọto gbe wọn wa ni, nitori mo mọ pe irin tiwọn le ma ba tiwa mu, nitori nnkan ti awa fẹẹ ṣe. Ki i ṣe pe Safu o le da gbogbo ẹ ṣe, oun naa lo kuku tiẹ ṣe e, ṣugbọn ara ẹ maa n ya to ba ti ri mi lẹyin ẹ nidii gbogbo nnkan to ba n ṣe.

Iya mi lo ya mi lẹnu, nigba ti wọn si fọ si leesi kan ti mo ra fun wọn nigba Ileya to kọja, niṣe ni wọn tun da bii ẹni ti nnkan kan ko ṣe rara, wọn ti fain ju. Awọn araale kọọkan naa tun n yọju, nitori ile Sẹki la ti ṣe e. Ọkọ ẹ ti kọkọ sọ fun un pe ko maa gbe ọmọ bọ lọhun-un, iyẹn ile wọn to wa lẹgbẹẹ ile wa, ṣugbọn nigba to ta ku pe ṣebi ile oun nibẹ, ọkọ oun naa lo si kọ ọ, ile toun ni, ki waa loun fẹẹ maa lọ sile mi-in si, nigba naa ni ọkọ ẹ gba fun un. Iyaale ẹ, Tomiwa, naa wa, emi ati Safu, ati ọrẹ Sẹki kan ti wọn ti jọ n ṣe latọjọ to pẹ.

Nigba ti yoo fi to aago mejila lọsan-an, gbogbo eyi ti a n wi yii ti kasẹ nilẹ, awọn alejo ti lọ. Safu ni oun fẹẹ gbe ounjẹ toun lọ si ṣọọbu, nitori oju ti n kan an. Emi ni mo ni ko ṣaa duro, ko jẹ ki gbogbo wa tọwọ bọwọ, nigba to jẹ araale kan ni gbogbo wa, ọjọ pataki, ọjọ ayọ si lọjọ naa. Ohun to si tiẹ n mu inu emi dun lọtọ ni orukọ ti mo ti sọ ọmọ yii, Oluwamayọwa ti mo ti pe e ni gbara ti wọn sọ fun mi pe wọn bi i, orukọ ti gbogbo wọn ba mi tẹ mọ ọn lori naa niyẹn. Sẹki ni orukọ ti iya sọ ọmọ loun fẹ, Iya mi ni awọn lawọn fun mi laṣẹ ki n sọ ọ lorukọ to wu mi, nibẹ lọrọ pari si.

Bi a ti jẹun tan ni Safu ti gbe baagi, o loun n lọ si ṣọọbu, ṣugbọn emi duro ti Iya mi, mo mọ pe bi wọn o lọ, n ko jẹ kuro nibẹ, abi nibo ni ki n fi wọn silẹ lọ. A tun ṣere diẹ si i, nigba to si n to asiko Ailaa, wọn ni ka maa waa lọ sile. Mo ni ki dẹrẹba tun gbe wọn pada sile, ko waa gbe emi to ba ti ja wọn, nitori mo ṣi fẹẹ jade. Bẹẹ lo si ṣe, igba to pada de ni mo too fi Sẹki ati awọn ọrẹ kọọkan to ti tun de silẹ, ọkan mi si balẹ pe yoo ri ẹni ba a ṣere, nitori Iya Tomiwa ti fẹsẹ palẹ diẹ, oun naa ti lọ nigba ti a ti sọmọ lorukọ tan.

Ọdo ẹni to n ba Safu ṣe ile ẹ ni mo fẹẹ lọ, o ti ni ki oun mu mi de saiti ki n wo ibi ti awọn ba iṣẹ de, pe iṣẹ ti lọ jinna nibẹ gan-an, ṣugbọn n ko fẹẹ sọ fun Safu funra ẹ, mo kan sọ pe mo fẹẹ jade ni. Amọ ọna naa buru, nigba ti a si debi kan ti a ko ribi kọja ni mo ni kọkunrin naa jẹ ka pada, pe to ba di ọjọ mi-in, a maa lọ. Mo tun beere lọwọ ẹ pe ṣe iṣẹ ṣaa n lọ gidi nibẹ, nigba to si ti sọ pe “Walahi”, mo mọ pe iṣẹ naa n lọ daadaa niyẹn. Mo ni to ba ti di ọjọ kẹta, a maa tete jade nile ni, mo fẹẹ foju ri ibẹ. Bi emi ṣe pada si ṣọọbu niyẹn.

Safu ni kọsitọma oun kan n bọ, bi a ṣe duro si ṣọọbu ti aago meje ti n lọọ lu ki kọsitọma too de niyẹn. Bo ṣe lọ la ti ilẹkun, lo ba dile. Ka too dele la ti n gbọ ariwo, Safu si n dapaara pe awọn araadugbo wa ti tun da pati kan silẹ niyẹn o. Emi naa ni ‘awọn oniranu!’ Afi bi a ṣe n sun mọle ti mo ri i pe ile wa ni nnkan ti n ṣelẹ. O ku diẹ ka wọle ni mo ri mọto meji kan to jẹ tawọn ọrẹ Alaaji, mẹsidiisi atijọ kan bayii ati ọkọ jiipu kan, awọn ọrẹ ẹ lo ni mejeeji, ọga ẹlẹran ni wọn l’Oṣodi wa. Ni mo ba fọwọ tọ Safu pe ọkọ ẹ lo n ṣe pati o.

Loootọ si ni, afi bi a ṣe kan wọn kuu, ti Alaaji ko sinu waiti leesi, ti iyawo e naa ru si i, iyẹn Aunti Sikira, lawọn ọrẹ wọn n pe e, ni wọn n mu oriṣiirisii ọti, igo bia sun lọ nibẹ, bẹẹ ni Aunti yẹn n lọ, to n bọ, wọn ti gbe kinni ikọrin wọn sita. O ya mi lẹnu. Mo mọ pe ikomọ Sẹki ni Alaaji n ṣe yii. Ko wa sibi ti a ti sọmọ lorukọ o, ko fi owo ọmọ ranṣẹ o, bẹẹ naa niyawo ẹ o, aṣe wọn ti jọ pa a, wọn ti kun un lati ṣe pati. Emi o binu o. Eyi to buru ni pe ko sẹni to lo ibomu ninu wọn, laye korona yii! Ti wọn ba waa mu baba yii pe o ṣe pati nkọ! Ki lo fẹẹ sọ! Emi o ni i da si i o. Abi ewo ni ki oyinbo muti ko jẹ kuku lọti n pa! Ta lo bimọ, ta lo n ṣekomọ!

Leave a Reply