Pasitọ ṣọọṣi tiyawo mi n lọ lo n yan lale, mi o fẹ ẹ mọ-Felix

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Kootu kọkọ-kọkọ to wa niluu Okitipupa, ti tu igbeyawo ọlọdun mẹrinla kan ka latari ẹsun agbere ṣiṣe ti olupẹjọ, Felix Awala, fi kan iyawo rẹ, Abilekọ Olufunkẹ Awala.

Felix to yan iṣẹ birikila laayo lo mori le ile-ẹjọ naa lọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun to kọja, to si rọ wọn lati tu igbeyawo ọlọdun gbọọrọ to wa laarin oun ati obinrin naa ka lori ẹsun agbere, iwa ọdaju ati pipa ojuṣe rẹ ti to fi kan an.

Ọkunrin ẹni ọdun mọkanlelogoji naa ni ọpọ igba loun ti gba iyawo oun mu lọrun ọwọ pẹlu pasitọ kan ti wọn jọ n yan ara wọn lale.

O ni bo tilẹ jẹ pe olujẹjọ ọhun kọkọ parọ fun oun pe baba ninu Oluwa ni pasitọ naa jẹ foun, aṣiri rẹ pada tu si oun lọwọ nikẹyin pe ibasepọ to wa laarin awọn mejeeji kọja ti pasitọ si ọmọ ijọ.

Felix ni ẹbẹ kan ṣoṣo toun bẹ ile-ẹjọ naa ni ki wọn tu ibaṣepọ awọn ka, nitori pe oun ko ni i le tẹsiwaju mọ pẹlu rẹ ninu igbeyawo. Bakan naa lo ni ki adajọ fi aṣẹ si i ki awọn ọmọ mẹrẹẹrin ti wọn bi le ni ikawọ oun fun itọju to peye.

Ọpọ igba n’ile-ẹjọ fi sun igbẹjọ siwaju ki wọn le fun olujẹjọ lanfaani lati waa sọ tẹnu rẹ, ṣugbọn to kọ ti ko yọju lai ni idi kan pato.

Eyi lo ṣokunfa bi alaga kootu kọkọ-kọkọ naa, Alagba Benson Ọmọtayọ, ṣe pinnu ati gbe idajọ rẹ kalẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Alagba Ọmọtayọ paṣẹ ki igbeyawo laarin Felix ati iyawo rẹ di tituka niwọn igba ti ko ti si ifẹ mọ laarin awọn mejeeji latari awọn ẹsun mẹtẹẹta ti olupẹjọ fi kan aya rẹ.

O ni oun fi aṣẹ si i ki olupẹjọ maa tọju awọn ọmọ wọn, eyi tọjọ ori wọn jẹ ọdun mẹrin, mẹwaa, mejila ati mẹrinla.

O ni olupẹjọ gbọdọ maa fun iya wọn laaye lati waa maa wo awọn ọmọ naa loorekoore.

Alagba Ọmọtayọ ni o di dandan fawọn mejeeji lati jọ maa gbọ bukata lori awọn ọmọ wọn.

Leave a Reply