Monisọla Saka
Pasitọ agba fun ijọ Dunamis International Gospel Center, Dokita Paul Eneche, ti ni ki wọn fi panpẹ ofin gbe awọn ‘Biṣọọbu’ eke ti wọn lọ sibi ti Tinubu ti kede Shettima gẹgẹ bii igbakeji rẹ ninu ibo aarẹ to n bọ lọna, eyi to waye niluu Abuja.
Ninu fidio kan ti iranṣẹ Ọlọrun naa gbe sori ayelujara lo ti sọrọ ọhun pe niṣe lo yẹ ki wọn fọwọ ofin mu awọn ayederu ‘Biṣọọbu’ ti wọn lọ si Abuja naa.
Eyi lo mu ki Pasitọ Eneche sọko ọrọ si ẹgbẹ oṣelu APC
ninu fidio kan to gbe sori Fesibuuku rẹ pe ki lo de ti wọn ran kankan mọ dide ori ipo aarẹ lọdun 2023 to bẹẹ.
O ni niṣe lo yẹ ki wọn fi panpẹ ofin gbe awọn ‘Biṣọọbu’ Ofege tawọn APC ko lọ sibi eto ọhun, ki wọn si ri i pe wọn foju bale-ẹjọ.
O ni, “Iwa ọbayejẹ ati ọjẹlu tawọn to fẹẹ dari Naijiria ni lọwọ lẹ ri yẹn. Ṣugbọn opin ti de fun wọn o. Wọn o ni i de ori ipo ti wọn lawọn n lọ yii. Ẹ fẹẹ fi mọdaru dori ipo, ẹ fẹẹ fi irọ pipa depo lẹyin tawọn eeyan yin ti ṣejọba fọdun mẹjọ”.
Amọ ṣa o, awọn ajọ to n ṣeto ipolongo ibo fun Tinubu ti ni irọ ni wọn n pa mọ awọn pe awọn haaya awọn Biṣọọbu ofege kan, wọn ni Biṣọọbu tootọ ni wọn, wọn o kan gbajumọ ni.
L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja yii, ni Bọla Tinubu ṣafihan gomina Borno tẹlẹ, Kashim Shettima, gẹgẹ bii ẹni ti yoo ṣe igbakeji rẹ lasiko ibo aarẹ. Nibẹ lawọn kan ti yọju, ti wọn pe ara wọn ni ‘Biṣọọbu’, ati ọmọ egbẹ agbarijọpọ awọn Onigbagbọ (CAN) tawọn ọmọ Naijiria si ri wi si eleyii pe ọpọlọpọ wọn ki i ṣe awọn olori ẹlẹsin ti wọn fi ara wọn pe.
Awọn ‘Biṣọọbu’ yii ni wọn sọ pe wọn haaya lati le bomi pana awuyewuye to wa nidii ọrọ Musulumi meji to fẹẹ jẹ aarẹ ati igbakeji ẹ, eyi tawọn ajọ CAN lodi si.