Olu-Theo Omolohun, Oke-Ogun
Ibi tọrọ tọkọ-taya kan ti wọn jẹ ojiṣẹ Ọlọrun ti wọn fẹẹ pin gaari laarin ara wọn maa ja si lẹnikan o ti i le sọ latari oriṣiiriṣii ẹsun ti Pasitọ Enoch Olubukọla Olukunle fi n kan iyawo rẹ, Pasitọ (Mrs) Christianah Oluwadamilare Olukunle, to si n bẹbẹ pe kile-ẹjọ tu awọn ka.
Olupẹjọ naa ni ọjọ karundinlọgbọn, oṣu kẹrin, ọdun 2009, iyẹn ọdun mọkanla sẹyin lawọn ti ṣegbeyawo nilana Kristẹni nile ijọsin wọn pe ni New Life Gospel Church, to wa laduugbo Isia, niluu Ṣaki, nipinlẹ Ọyọ, tawọn si ti bi ọmọ mẹta, Isreal, Janet ati Deborah.
Gẹgẹ bo ṣe ro o lẹjọ ni kootu, Enoch ni latigba tawọn ti fẹra ni ko ti si isinmi ati igbe aye alaafia laarin awọn, o ni oun kan n pa iwa iyawo oun mọra ni gẹgẹ bii ọkunrin nitori obinrin naa ki i gbọ ibawi, ko si ba oun fọwọsowọpọ lori bi ijọ Ọlọrun yoo ṣe gberu si i. Kaka bẹẹ, awọn nnkan ija bii ọbẹ tabi orogun ọka lo fi maa n dunkooko mọ oun ti ede-aiyede ba ṣẹlẹ laarin awọn, tabi ko maa leri pe oun yoo ba oun lorukọ jẹ laarin ilu, oun yoo si tu ijọ mọ oun lori.
Nigba ti ile-ẹjọ beere nipa awọn igbesẹ to to gbe lati wa ojutuu si aawọ to n bẹ silẹ laarin wọn, baale ile naa ṣalaye pe ọpọ igba loun ti mu ẹjọ rẹ lọ sọdọ awọn obi rẹ atawọn alagba ijọ toun n ṣe oluṣọ-aguntan rẹ, ṣugbọn to jẹ kaka kewe agbọn ọrọ naa dẹ, niṣe lo n le si i.
Pasitọ Enoch ni pabambari toun ri lẹnu ọjọ mẹta yii to waa mu koun pinnu lati kuku fopin si igbeyawo naa ko ṣẹyin bawọn awọn mọlẹbi iyawo oun ṣe bẹrẹ si i fẹsun kan oun kaakiri pe niṣe loun fẹẹ fi iyawo naa atawọn ọmọ mẹtẹẹta to bi foun ṣoogun owo, eyi loun si ṣe fẹẹ kọ ọ, tori ẹsun naa ti n ran kiri ilu.
O waa rọ ile-ẹjọ lati tu ajọṣepọ naa ka, ki wọn si ba oun gba awọn ọmọ oun.
Ṣugbọn nigba ti wọn ni ki iyawo rẹ fesi sawọn ẹsun tọkọ rẹ fi kan an, niṣe lobinrin naa poṣe, to ni awijare lasan ni ọkunrin naa n wi, irọ nla lo si n pa mọ oun. Lo ba fa fọto kan yọ ninu baagi rẹ lati fi ṣe ẹri pe ọkọ oun ti lọọ ṣe igbeyawo bonkẹlẹ kan nipamọ, tori ẹ lo ṣe n wa ọna lati kọ oun silẹ.
O lawọn mọlẹbi rẹ gan-an jẹrii si iwa aiṣootọ ati ọdalẹ to n hu, ati bo ṣe n foju oun gbolẹ latigba tawọn ti fẹra.
Adajọ-binrin M. A. Aworeni gba abilekọ naa niyanju lati wa lọọya to maa ba a ṣa awọn ẹri rẹpẹtẹ to loun ni lọwọ ta ko ọkọ rẹ jọ, ti yoo si ran an lọwọ lati ṣalaye awijare rẹ lọna to nitumọ nile-ẹjọ
Adajọ ni kawọn mejeeji pada wa lọjọ kọkanlelogun, oṣu yii, pẹlu agbẹjọro wọn, ki igbẹjọ ati idajọ le tete waye.