Faith Adebọla
Pasitọ oniṣẹ-iyanu lawọn eeyan mọ ọn si, titi dasiko ta a si fi n ko iroyin yii jọ, ko sẹni to mọ pato orukọ ẹ gan-an, amọ o jọ pe orukọ oniṣẹ-iyanu ti wọn fun oludisilẹ ṣọọṣi yii ro o gidigidi o, tori bii iṣẹ iyanu niwa to hu jọ loootọ, ọmọọjọ ẹ mẹwaa lo fun loyun lẹẹkan naa lasiko tawọn yẹn wa iṣẹ-iyanu wa si ṣọọṣi ẹ, eyi lo si mu kawọn araalu ẹ fibinu le e jade niluu wọn, wọn lawọn o fẹ iru pasitọ ọran bii tiẹ yii, ni wọn ba tun fibinu dana sun ṣọọṣi to da silẹ ọhun.
Abule kan ti wọn n pe ni Umuidoko Ogrute, niluu Enugu Ezike, nijọba ibilẹ Ariwa Igbo Eze, nipinlẹ Enugu, niṣẹlẹ naa ti waye lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹrin yii.
Ori-oke kan ni wọn lọkunrin to pera ẹ ni pasitọ yii lọọ kọ ṣọọṣi rẹ ọhun si, tawọn eeyan si n lọ sibẹ, paapaa awọn obinrin ti wọn nilo iṣẹ iyanu laye wọn.
Ọkan ninu awọn obinrin to n jọsin ni ṣọọṣi ọhun lo jẹ ki akara tu sepo nipa pasitọ yii, wọn lo ti ṣe diẹ tawọn mọlẹbi obinrin ta a forukọ bo laṣiiri yii ti ri i pe o ti fẹra ku, ko too di pe o jẹwọ fawọn eeyan ẹ kan pe pasitọ naa lo foun loyun.
Ẹnikan to sọro nipa iṣẹlẹ yii sọ pe: “Niṣe ni pasitọ yii maa n mu awọn obinrin ṣọọṣi ẹ lọ sori oke lati lọọ gbadura fun wọn, o fẹrẹ jẹ kidaa awọn obinrin lo wa ninu ṣọọṣi ẹ naa. Niṣe lo maa n riran si wọn, o l’Ọlọrun maa n fi han oun bi wọn ṣe le ri ọkọ to lowo bii ṣẹkẹrẹ fẹ, iyẹn to ba jẹ ẹni to n wa ọkọ, tabi bi baale wọn ṣe le di olowo yalumọ, tawọn naa yoo si maa fẹla, eyi lo maa n mu kawọn obinrin rọ lọ si ṣọọṣi ẹ, ọpọ wọn ko si i ni i mọna ile mọ ti wọn ba ti dọhun-un, niṣe lo maa mu wọn sabẹ aabo, tabi ko yan igbele fun wọn loju-ẹsẹ.
“Lori oke naa lo ti n ko ibasun fun wọn, niṣe lo n to tọọnu lori wọn bo ṣe wu u. Ti wọn ba si ti loyun, ibẹ naa lo ti n ba wọn ṣẹ ẹ, ti yoo si tun maa ba wọn su niṣo.
“Nigba tọwọ palaba ẹ maa ṣegi, ọkan ninu awọn obinrin to fun loyun jẹwọ fawọn mọlẹbi ẹ, nigba ti wọn si tọpasẹ pasitọ yii de ibi to ti n huwa buruku naa, obinrin olobinrin rẹpẹtẹ lo wa nibẹ, mẹwaa ninu wọn lo ti loyun, awọn kan jẹwọ p’awọn ti ṣẹ oyun tiwọn, wọn loun naa lo ṣẹyun fun awọn.”
Ṣa, awo ọrọ yii to lu lo mu kawọn ọdọ agbegbe naa fariga lọjọ Ẹti, Furaidee, ọhun, ti wọn fi lọọ dana sun ṣọọṣi ati abẹ aabo to kọ sibẹ, ti wọn ko ẹru pasitọ yii sinu baagi ghana-must-go kan, ni wọn ba ta a lọji, wọn sin in jade niluu naa, wọn si bu yeepẹ ilu ọhun sinu aṣọ ti wọn ta ni koko kan fun un, aroko eyi to tumọ si pe ko gbọdọ tun ṣeeṣi da ẹsẹ rẹ tẹlẹ ninu ilu wọn mọ. Wọn ni to ba ṣe bẹẹ pẹnrẹn, ko fara mọ ohun toju rẹ ba ri ni.