Njẹ ẹ gbọ nipa pasitọ kan to ni oun nigbagbọ ninu Jesu, ọmọ ẹyin rẹ tootọ loun n ṣe. Pasitọ to ni ki wọn sin oun laaye, oun yoo ji dide ninu oku lọjọ kẹta bii Jesu, pasitọ ọhun ti ku lẹyin ti wọn gbe e sin laaye o.
Pasitọ James Sakala lọkunrin naa n jẹ, ọdọmọde pasitọ ni, nitori ọjọ ori ẹ ko ju mejilelogun lọ (22).
Orilẹ-ede Zambia ni ṣọọṣi rẹ wa, orukọ ṣọọṣi naa ni Zion Church.
Awọn to mọ ọn sọ pe igbagbọ rẹ le pupọ, wọn ni ko si ara ti ko le da, nitori ohun to maa n sọ ni pe bẹẹ ni Jesu ṣe to fi ṣe aṣeye, ti gbogbo aye fi n wari fun un.
Laipẹ yii ni wọn lo bẹrẹ iwasuu òdì kan, to bẹrẹ si i beere lọwọ awọn ọmọ ijọ rẹ pe ṣe wọn nigbagbọ ṣa. Wọn ni Pasitọ Sakala sọ pe njẹ wọn mọ pe bi wọn ba gbe oun sin laaye, oun yoo ji dide ninu oku lọjọ kẹta, gẹgẹ bi Jesu ṣe ṣe nigba aye ẹ.
Awọn ara ṣọọṣi ti igbagbọ wọn ko gbe e sọ fun un pe awọn ko fẹ ko tiẹ dan iru rẹ, wo, bo ti wu ki kinni ọhun da a loju to, wọn ni ko ma ṣe bẹẹ rara. Ṣugbọn awọn kan ko fẹẹ kọrọ si i lẹnu, wọn ni ẹni mimọ ninu Oluwa ni, ko si le sọ ohun ti ko da a loju.
Koda, awọn kan beere lọwọ Sakala pe ki lo de to fi fẹẹ gbe igbesẹ to lewu yii, ohun to sọ fun wọn ni pe Jesu ni kawọn ọmọ ẹyin oun maa ṣeranti oun boun ba lọ tan, o ni ajinde rẹ pada lo n wi, ki i ṣe ki wọn kan maa lọọ jẹ akara alaiwu ni ṣọọṣi nikan.
Wọn ni Pasitọ James Sakala sọ pe ‘Ẹyin ti igbagbọ yin lẹ yii, ẹ gbe Sakala yii sin laaye, ẹ o si ri i pe yoo ji dide pada ninu oku, yoo si maa mi pada gẹgẹ bii alaye.
Bẹẹ lo si ṣe ti awọn ọmọ ijọ ti wọn fẹẹ wo miraku, iyanu nla ẹlẹkeeji lẹyin iku Jesu, gbe pasitọ wọn si koto to ti gbẹ silẹ.
Wọn ni aṣọ funfun ni Sakala fi pakaja bii Jesu, o si wọ bata rọba alawọ buraun si i, o dubulẹ sibẹ, wọn n rọ yẹẹpẹ bo o looye, awọn ọmọ ijọ rẹ si n kọrin ogo fun un bi wọn ṣe n sin in, wọn fijo yẹ ẹ si de ajule ọrun.
Nigba tọjọ kẹta pe e, wọn ko yẹpẹ kuro lori Pasitọ Sakala, oorun buruku lo kọkọ bẹrẹ si i bo wọn. Ọkunrin naa ti ku sabẹ yẹẹpẹ, o ti n jẹra.
Wọn ni wọn ri ẹjẹ lara rẹ, wọn ri ikun pẹlu, o jọ pe nibi to ti n gbiyanju ati jade labẹ ilẹ ni ikun imu rẹ ọtun ti bọ si tosi, to pọ rẹpẹtẹ, to yi i lara nibi to ti n gbiyanju lati bọ lọwọ iku.
Ṣọọṣi rẹ ti dahoro wayi, iyẹn nikan si kọ, awọn ọlọpaa Geza Phiri to ti ṣẹlẹ ṣi n wa awọn ọmọ ijọ to lọwọ si isinku abaadi naa, wọn ni mireku buruku ti wọn fẹẹ ri ni wọn tori ẹ pa pasitọ wọn nipa gbigbe e sin laaye.