Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Pasitọ Timothy Oluwatimilẹyin ree, oludari ijọ Spirit Filled International Christian Church, Olomoore, l’Abẹokuta. Oun lawọn ọlọpaa ti mu bayii, to si ti wa lẹka to n gbọ ẹsun ṣiṣe ọmọ niṣekusẹ. Iyawo ọmọ ijọ ẹ atawọn ọmọ meji tobinrin naa bi lo gbe pamọ sile, to n ba wọn lo pọ.
Ọkọ obinrin naa lo mu ẹjọ lọ si tẹsan ọlọpaa Adatan, oun ati ọkan lara awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn obinrin. Ọkọ obinrin naa ṣalaye pe Pasitọ Timothy fi ẹtan mu iyawo atawọn ọmọ oun obinrin meji sọdọ, o si n ba awọn mẹtẹẹta laṣepọ.
Ifisun yii lo jẹ kawọn ọlọpaa lọ si ṣọọṣi Pasitọ Oluwatimilẹyin, ti wọn si mu un.
Pasitọ naa kuku jẹwọ fun wọn, ohun to sọ fawọn ọlọpaa ni pe ija kan to waye laarin obinrin naa ati ọkọ ẹ loun lo lati wọle si iyawo ile ọhun lara.
O ni anfaani ija naa loun lo lati fi tan obinrin yii atawọn ọmọ ẹ meji pe ki wọn maa waa gbe lọdọ oun na, to fi di pe oun bẹrẹ si i ba a sun pẹlu awọn ọmọ rẹ obinrin meji to ko wa.
O waa ni ki wọn jọwọ, dariji oun, oun o tun ni i ṣe bẹẹ mọ laye.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle ti paṣẹ pe ki wọn gbe pasitọ to n ba iya atọmọ sun naa lọ si ẹka to n ri si ijinigbe ati ṣiṣe ọmọde niṣekuṣe.
Ni bayii, wọn ti gbe Pasitọ Timothy Oluwatimilẹyin lọ sẹka naa, yoo lọọ sọ tẹnu ẹ ni kootu laipẹ.