Faith Adebọla
Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), ti ni ibi yoowu ki abajade esi idibo gbogbogboo to n lọ lọwọ yii yọri si, wọn lawọn maa tẹwọ gba a, awọn aa si fara mọ ọn.
Ọga agba fun igbimọ to n polongo ibo fun Alaaji Atiku Abubakar to jẹ oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu ọhun, Aminu Tambuwal, lo sọrọ yii laaarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keji yii.
Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ ni ile rẹ to wa nijọba ibilẹ Tambuwal, nipinlẹ Sokoto, Gomina ipinlẹ Sokoto naa sọ pe ko si nnkan babara tabi ma-jẹ-a-gbọ kan ninu idije ati idibo, ohun to ṣe koko ni ki eto naa ma ti ni eru tabi ojooro ninu.
O ni ẹgbẹ oṣelu awọn jẹ ẹgbẹ to bọwọ fun ofin, o si jẹ ẹgbẹ to gbagbọ ninu ilana ati alakalẹ.
O ni: “A nigbagbọ pe latọdọ Ọlọrun Olodumare ni kadara gbogbo eeyan ti wa, Oun lo n fun ẹni to ba wu u ni ipo ati agbara, ayanmọ ko si le tase. Tori bẹẹ, tinu-tinu ati tọkan-tọkan la maa fi tẹwọ gba ibi yoowu ki abajade eto idibo yii yọri si.” Gẹgẹ bo ṣe wi.
Titi dasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ ni iṣiro, aropọ ati kika ibo ṣi n lọ lọwọ kaakiri awọn ipinlẹ mẹrindinlogoji ati olu-ilu ilẹ wa, Abuja, latari eto idibo sipo aarẹ, awọn aṣofin agba atawọn ọmọleegbimọ aṣoju-ṣofin to waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu yii.
Ẹgbẹ oṣelu PDP wa lara awọn ẹgbẹ oṣelu mejidinlogun to kopa ninu eto idibo naa.