Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ṣe owe Yoruba lo sọ pe aileeja ni i jẹ ita baba mi ko de ibi kan. Eyi lo ṣe mọ ẹgbẹ oṣelu PDP lara pẹlu bi wọn ṣe na Gomina Oyetọla mọ wọọdu to wa nitosi ile ijọba, niluu Oṣogbo.
Ireti gbogbo eeyan ni pe ẹgbẹ APC lo yẹ ko rọwọ mu ni adugbo yii nitori itosi ọfiisi ati ibi ti gomina n gbe lo wa, ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ nigba ti wọn bẹrẹ si i ka ibo agbegbe naa, to si foju han pe ẹgbẹ alatako lo yege nibẹ.
Ninu esi idibo Agọwande/Oṣogbo GRA/Governor’s office, to wa ni Ọlọrunda yii, ibo mẹtadinlọgọfa (117) ni ẹgbẹ oṣelu PDP ri nibẹ, nigba ti ẹgbẹ to n ṣejọba lọwọ, APC, ni ibo ọgọrun-un le mẹfa (106). Accord ni ibo meji pere. SDP ni ibo ẹyọ kan.