PDP yan Ọbaseki ati Makinde lati ṣaaju ipolongo atundi ibo ileegbimọ aṣoju-ṣofin ti yoo waye l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ẹgbẹ oṣelu PDP ti kede orukọ Gomina ipinlẹ Edo, Godwin Ọbaseki ati ojugba rẹ nipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde, gẹgẹ bii adari igbimọ to fẹẹ polongo fun oludije wọn ninu atundi idibo ile-igbimọ aṣoju-ṣofin l’Abuja, eyi ti yoo waye nijọba ibilẹ Ariwa ati Guusu Akurẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii.

Ikede yii lo waye ninu atẹjade kan ti Debọ Ologunagba to jẹ Alukoro fun ẹgbẹ PDP lorilẹ-ede yii fi sita lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Ni ibamu pẹlu atẹjade ọhun, Ọbaseki ni wọn yan gẹgẹ bii alaga igbimọ ipolongo naa, nigba ti Makinde duro bii igbakeji rẹ.

Lara awọn ọmọ ẹgbẹ ti yoo tun ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn mejeeji ni gomina ipinlẹ Ondo ana, Oluṣẹgun Mimiko, oludije fun ẹgbẹ PDP ninu eto idibo gomina to kọja, Amofin Agba Eyitayọ Jẹgẹdẹ, Debọ Ologunagba funra rẹ, igbakeji gomina tẹlẹ, Ọtunba Ọmọlade Oluwatẹru, Sẹnetọ Abiọdun Olujimi, Sẹnetọ Ayọ Akinyẹlurẹ, Sẹnetọ Nicholas Tofowomọ atawọn mẹtadinlogun mi-in.

Aaye aṣoju-ṣofin l’Abuja ọhun lo si silẹ latari bi Ọnarebu Adedayọ Ọmọlafẹ, ẹni tọpọ awọn eeyan mọ si Expensive, ṣe deedee ku lojiji ninu oṣu kẹfa, ọdun to kọja.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja, lajọ eleto idibo kede fawọn eeyan pe awọn ti mu ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keji ọdun 2022, fun atundi eto idibo naa, leyii to ṣokunfa bi awọn ẹgbẹ oṣelu to fẹẹ kopa ṣe sare ṣeto idibo abẹle wọn lati yan oludije ti yoo ṣoju ẹgbẹ wọn ninu atundi idibo naa.

Eyi lawọn ẹgbẹ oṣelu meje ti wọn fẹẹ kopa ninu eto idibo ọhun atawọn oludije wọn.

Ọlawale Oyemakinde, Accord Party, Fadekẹ Felicia, African Democratic Party, Alade Mayọkun, All Progressives Congress, Joseph Ajayi, All People’s Party, Johnson Oluwasuyi, National Redemption Movement, Olumuyiwa Adu, People’s Democratic Party ati Ọpawọle Tajudeen, Social Democratic Party.

Leave a Reply