Jọkẹ Amọri
‘Pẹlu bi mo ṣe siṣẹ sin gomina Ọṣun tẹlẹ, Ọgbẹni Rafiu Arẹgbẹṣọla, fun odidi ọdun mẹjọ, ko si idi fun un lati ma ṣatilẹyin fun mi.’ Gomina Ọṣun bayii, Ọgbẹni Gboyega Oyetọlan lo sọ eleyii di mimọ nigba to n sọrọ lori redio kan nipinlẹ naa lati sami ayẹyẹ ọdun kejidinlogun ti wọn da ipinlẹ Ọṣun silẹ.
Oyetọla ni Ọlọrun, ati awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun ni yoo sọ boya oun maa pada sileejọba lọdun to n bọ lati tun di gomina lẹẹkeji.
O fi kun un pe Arẹgbẹṣọla kọ lo ran awọn ẹgbẹ kan ti wọn n pe ara wọn ni ‘The Ọṣun Progressive’ (TOP), ni iṣẹ ti wọn n jẹ, gbogbo ohun ti wọn si n sọ pe wọn ko ni i ṣatilẹyin foun ninu eto idibo ọdun to n bọ ki i ṣe ero ọkan gomina tẹlẹ to ti di minisita fun eto abẹle bayii.
Oyetọla ni, ‘Mo gbagbọ pe ẹgbọ mi ni Arẹgbẹṣọla, mo si gbagbọ pe ni gbogbo ọna ati ni gbogbo igba ni yoo fi maa wa aṣeyọri mi nitori emi naa ṣiṣẹ takuntakun fun odidi ọdun mẹjọ fun aṣeyọri oun paapaa.
‘Ti awọn kan ba jade ti wọn ni awọn ko ni i ṣatilẹyin fun mi, mi o ro pe ero ọkan Arẹgbẹ ni wọn n sọ. Gẹgẹ bi mo ṣe sọ, ẹgbọn mi ni, mi o si ri idi to maa fi ni oun ko ni i ṣatilẹyin fun mi ti awọn araalu ba fẹ mi.’
O fi kun un pe oun ko ti i ronu lori saa keji bayii, ohun to wa lọkan oun ni bi oun yoo ṣe siṣẹ sin awọn eeyan oun.