Adewale Adeoye
Ile-ejọ kan to n gbọ ẹsun magomago to su yọ lakooko ibo aarẹ to waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2023 yii, niluu Abuja, ‘Presidential Election Petition Tribunal’, ti paṣẹ fun oludije funpo aarẹ lẹgbẹ Labour Party, Peter Obi ati ẹgbẹ oṣelu rẹ ti wọn pe aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nilẹ wa, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu lẹjọ lori bi ajọ eleto idibo INEC ilẹ wa ṣe kede rẹ pe oun lo wọle pe ki wọn mu gbogbo ohun ti wọn fẹẹ fi pẹjọ lori ọrọ wọn wa sopin laarin ọsẹ mẹta si asiko yii.
Bakan naa nile-ejọ ọhun tun rọ Tinubu ati ajọ INEC pe kawọn naa mu gbogbo ohun ti wọn fẹẹ fi gbe ẹjọ wọn lẹsẹ pe Tinubu lo wọle wa sile-ejọ naa laarin ọjọ marun-un si akoko yii.
Alaga igbimọ adajọ ẹlẹni marun-un to n gbọ ẹjọ naa, Adajọ Haruna Simon Tsammani, lo sọrọ ọhun di mimọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, nigba ti igbẹjọ n lọ lọwọ lori ẹjọ ti Obi ati ẹgbẹ LP pe Tinubu pe oun kọ lo wọlẹ ibo ọhun.
Adajọ Tsammani ni ọhun ti sọ pe ki Obi bẹrẹ si i mu gbogbo ẹri rẹ ati ohun to fẹẹ fi gbe ọrọ rẹ lẹsẹ wa sile-ẹjọ naa, bẹrẹ lati ọgbọnjọ, oṣu Karun-un, ọdun yii, di ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹfa, ọdun yii kan naa.
Bẹẹ o ba gbagbe, lọọya Obi, Ọjọgbọn Awa Kalu, (SAN), rọ ile-ejọ naa pe ki wọn faaye ọsẹ meje gba Peter Obi lati fi mu awọn ohun to fẹẹ fi gbe ẹjọ rẹ lẹṣe wa sile-ẹjọ naa lati fi han pe ki i ṣe Tinubu lo wọle.
Ṣa o, ile-ejọ naa ti rọ awon eeyan tọrọ kan pe ki wọn ṣohun gbogbo ni kiakia, ki ẹjọ wọn ma baa falẹ rara.