Monisọla Saka
Gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹri, to tun jẹ oludije sipo Aarẹ ilẹ wa labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party, lọdun 2023,Peter Obi, ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ti ijọba ipinlẹ Eko gbe lori awọn ọmọ ipinlẹ Ọṣun ti wọn n gbe l’Ekoo.
Awọn ọmọ ipinlẹ Ọṣun, tijọba ipinlẹ Eko he kaakiri awọn adugbo bii Ajah, TBS ati Lagos Island, ti wọn si fi mọto ru wọn lọ si ilu wọn, lo kọ Obi lominu to fi sọrọ naa. O ni titẹ ẹtọ eeyan gẹgẹ bii ọmọ orilẹ-ede yii loju mọlẹ, ni nnkan tijọba naa ṣe.
Obi ni, “Inu mi bajẹ gidigidi, bẹẹ ni iroyin to de etiigbọ mi pe ijọba Eko lọọ ja awọn ọmọ Ọṣun ju silẹ nipinlẹ wọn ka mi lara. Ọrọ yii ko kan ipinlẹ Ọṣun nikan, bi ko ṣe gbogbo ọmọ orilẹ-ede Naijiria ti wọn mu ọrọ iṣọkan, iṣedeede ati idajọ ododo ni pataki.
“Mo ri iwa yii bii eyi to buru gan-an, nitori ipa ti yoo ni lori ajọṣepọ ati idagbasoke ti a n wa lati ọjọ yii. Gẹgẹ bii ẹni to n pe fun iṣọkan ilẹ Naijiria, mi o fara mọ awọn iwa bii iyanjẹ, idẹyẹ-si-ni, ati titẹ ẹtọ ẹni loju mọlẹ.
“Gbogbo ọmọ Naijiria, lai fi ti ipinlẹ ti wọn ti wa tabi ibi ti wọn n gbe ṣe, ni wọn lẹtọọ si ki wọn fi ọwọ ati apọnle ba wọn lo. Ẹ jẹ ka ranti pe ọmọ Naijiria ni gbogbo wa, ti kadara so wa papọ. Ati pe ojuṣe gbogbo wa ni lati ṣe igbelarugẹ fun iṣọkan, iṣedeede ati idajọ ododo, ati lati dide ta ko iwa ijegaba ati aiṣododo. Iwe ofin ilẹ Naijiria fi ẹnikọọkan wa lọkan balẹ lati gbe, ati lati maa wa jijẹ mimu ni apa ibi yoowu lorilẹ-ede yii.
“Mo n rọ gbogbo ọmọ Naijiria, ki wọn ṣe suuru, ki wọn ma si tura silẹ gẹgẹ ba a ṣe n duro de abajade esi iwadii.
Awọn oṣiṣẹ eleto aabo nipinlẹ Ọṣun naa n mojuto ọrọ yii lati ri i daju pe awọn ọdọ ti wọn fi sọko sile naa wa lalaafia.
“Pẹlu ifọwọsowọpọ gbogbo wa, ẹ jẹ ka a gbiyanu lati ṣe idasilẹ orilẹ-ede Naijiria ti wọn ti n buyi ati apọnle fawọn eeyan ẹ, lai wo bi wọn ṣe jẹ ati ibi ti wọn ti wa ,tabi ibi ti wọn n gbe. Ilẹ Naijiria ọtun to ni iyatọ le wa si imuṣẹ. Ẹ jẹ ka a ṣiṣẹ tọ iṣọkan”.
Ọrọ Peter Obi yii waye, latari awuyewuye kan to n lọ lori ayelujara pe awọn ọlọpaa ko awọn eeyan kan lagbegbe Erekusu ipinlẹ Eko, agaga lẹyin ti wọn ṣawari ile tawọn eeyan n gbe labẹ biriiji Dolphin Estate, Ikoyi, nipinlẹ Eko.
Pupọ ninu awọn eeyan yii ni wọn fẹsun kan ijọba ipinlẹ Eko pe wọn gbe bọọsi nla kalẹ ti wọn fi ru awọn eeyan naa lọ siluu Ileṣa, nipinlẹ Ọṣun ti wọn ti wa.
Ọrọ yii, ni wọn lo bi gomina Ademọla Adeleke ti ipinlẹ Ọṣun ninu, paapaa ju lọ, bi wọn ṣe n ja wọn kalẹ kaakiri awọn agbegbe bii orita oju ọna marosẹ Ileṣa si Akurẹ, Breweries, Ileṣa, Ìbòdì, Igi ńlá, titi de oju ọna Ifẹ, oju ọna marosẹ Ìmèlu, ati ikorita marosẹ Ìperindó.
Kọmiṣanna fọrọ iroyin nipinlẹ Eko, Gbenga Ọmọtọshọ, to pada fidi ọrọ naa mulẹ ṣalaye pe awọn janduku tawọn ṣa kaakiri ilu atawọn ti awọn doola nibi eto ifọlumọ kuro lọwọ ewu, ti wọn le ni irinwo lawọn ko ranṣẹ sile.
Ninu awọn eeyan irinwo ati aadọta (450), ti wọn ni janduku ati baara ni wọn n ṣe ti wọn ko yii, ọọdunrun ati mọkanlelaaadọrin (371), ni wọn ni wọn bẹbẹ pe ki ijọba ipinlẹ Eko da awọn pada siluu awọn, nitori inira naa pọ ju fawọn.
Awọn mọkandinlọgọrin (79) to ku, ni Kọmiṣanna yii sọ pe awọn ti ko lọ sibudo ti wọn ti n ba awọn eeyan sọrọ lati yi igbe aye wọn pada si ti daadaa (rehabilitation centre), latari ami aigbadun ti wọn ri lara wọn.