Jọkẹ Amọri
Oludije funpo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi, lo jawe olubori ni ibudo idibo kan lara awọn ibi idibo to wa nile agbara, iyẹn Aso Rock, ninu idibo to waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, yii.
Lẹyin ti wọn pari idibo agbegbe naa ni awọn to n ṣakoso ibo nibẹ ka a, to si fi han pe ẹkọ ṣoju mimu fun gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹ ọhun.
Ni ibudo idibo aadoje din ẹyọ kan(139) to jẹ ọkan lara awọn ibudo idibo to wa ni Aso Rock, niluu Abuja, ni Peter Obi ti ni ibo mẹtadinlogun, nigba ti oludije funpo aarẹ lẹgbẹ APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu, ni ibo mẹfa, ti oludije lẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar, ni ibo mẹta pere.
Pẹlu esi idibo yii, Peter Obi lo bori ninu ibudo idibo akọkọ ti wọn yoo kọkọ kede rẹ ni Aso Rock.