Peter sọ fawọn ọrẹ ẹ pe ọga oun lowo lọwọ, n l’Arowolo atawọn ẹgbẹ ẹ ba lọọ digun ja a lole l’Ekoo

Aderounmu Kazeem

 

Bii ajẹ to jẹ̣ eepo ọbọ ni ọdomọkunrin kan, Arowolo Ibrahim, ṣe n ka pẹlu awọn ẹlẹgbẹ ẹ ti wọn jọ digunjale, nigba ti kọmiṣanna ọlọpaa ṣafihan wọn han ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Eleweeran, niluu Abẹokuta, l’Ọjọruu, Wẹsidee, nigba ti wọn ko wọn dewaju awọn oniroyin.

Mẹrin lawọn janduku ọmọ keekeeke yii ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mejidinlogun si mẹrinlelogun. Awọn eeyan naa niwonyi; Arowolo Ibrahim, Yakubu Ibrahim, Yusuf Alani Azeez, Ṣowẹmimọ Faruq ati Peter Okenu, ọmọ Ibo ti wọn loun lo ṣatọna wọn debẹ.

Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kejila, ọdun 2020, ni wọn sọ pe ọwọ tẹ awọn eeyan yii ni kete ti ọkunrin ti wọn digun ja lole, Stephen Anyi, fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa niluu Ifọ, ipinlẹ Ogun, pe awọn janduku kan kọ lu oun nile oun.

 

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe alaye ti ọkunrin to pe awọn yii ṣe ni pe nile oun to wa ni Kajola Phase II, n’Ifọ, ni wọn waa ka oun mọ, ati pe oju windo ni wọn gba wọle.

Mọto ẹ, Toyota Highlander, ti nọmba ẹ jẹ KJA 38 FZ, naa pẹlu awọn nnkan ti wọn ko lọ pẹlu laptop, foonu alagbeeka ati owo. Awọn ọlọpaa sọ pe loju-ẹsẹ naa ni teṣan ọlọpaa ti bẹrẹ iṣẹ, ti ọwọ si tẹ awọn janduku yii laduugbo Mushin, l’Ekoo, nibi ti wọn ti fẹẹ ta awọn ẹru ti wọn ji ko ọhun.

Ileeṣẹ ọlọpaa fi kun un pe awọn ọdaran ti wọn mu yii ti jẹwọ, alaye ti wọn si ṣe ni pe Peter Okenu, ẹni ti ṣe ọmọọṣẹ ọkunrin ọmọ Ibo ti awọn lọọ ja lole yii lo ni ki awọn waa ko ile ọhun.

Wọn ni funra Peter lo sọ pe ki awọn maa bọ wa, owo rẹpẹtẹ lawọn pa ni sọọbu awọn lọjọ naa, ile si lawọn n ko o lọ.

ALAROYE gbọ pe oun yii kan naa lo tun ṣi windo fun wọn nigba ti wọn de loru. Awọn ọlọpaa sọ pe Peter yii nikan ni wọn ko gba foonu ẹ, bẹẹ ni wọn ko tun fiya jẹ pẹlu, eyi to jẹ ki wọn tete fura si i ki awọn ole paapaa too sọ pe oun gan an lo ni ki awọn maa bọ waa jale nile ọga oun.

Ninu ifọrọwerọ wa pẹlu awọn janduku yii, alaye ti Arowolo Ibrahim ṣe ni pe Peter lo sọ fun awọn ki awọn waa jale nibẹ. O ni ọkunrin kan naa wa to sun mọ ọn daadaa, Ganiu lorukọ ẹ n jẹ, oun lo sọ fun pe awọn n ta daadaa ni gbogbo asiko ọdun yẹn, ati pe owo bii miliọnu meje naira lawọn maa n gbe lọ sile lojumọ.

Ọdọmọkunrin to n ṣiṣe kafinta yii sọ pe miliọnu meje naira ti oun gbọ lo jẹ ki eti oun na, ti oun si sọ fun un pe ko ṣeto bi awọn yoo ṣe ra nnkan ti awọn yoo fi ṣiṣẹ naa.

Ẹgbẹrun mẹta naira lo sọ pe ọmọ Ibo ko fun awọn, ada si lawọn fi ra.

O ni bo ṣe di oru lawọn gba ile ọkunrin naa lọ, nigba ti awọn si debẹ, niṣe lo sọ pe oun ko gbe owo kankan wale, nigba ti awọn naa si tu gbogbo ile ọhun yẹbẹyẹbẹ, awọn ri i pe ko si miliọnu meje kankan nibẹ, nibi ti awọn ti sọ fun un pe ko fun awọn ni ohunkohun to ba ni niyẹn, to si ko ẹgbẹrun lọna ọgọta (N60,000) naira jade.

Arowolo sọ pe loju-ẹse naa lawọn gba kọkọrọ mọto Highlander ẹ, bẹẹ lawọn gba foonu atawọn dukia mi-in ninu ile wọn.

O fi kun un pe nigba ti awọn wọle sọdọ ọmọ Ibo to ni ki awọn waa jale ọhun, oun ko jẹ ki awọn yooku oun na an, bẹẹ loun tun sọ pe ki wọn da foonu ẹ ti wọn gba lọwọ ẹ pada fun un.

O ni bi awọn ṣe kuro nibẹ niyẹn ti awọn si kan’na si igbo, ti awọn n fa a lọ ninu mọtọ onimọto ti wọn gbe ninu ile ọkunrin naa.

Nibi ti wọn ti n lọ lo ti sọ pe ọwọ ọlọpaa ti tẹ awọn, ti awọn naa ko si janpata lati ṣe jẹẹjẹ pẹlu wọn.

Oṣu kan lo sọ pe awọn ti kọkọ lo l’Ekoo, ki wọn too ko awọn wa si olu ileeṣẹ ọlọpaa ni Eleweran, niluu Abẹokuta.

Ọmọ yii sọ pe ọmọ ọdun mẹrinlelogun loun, ọmọ Ijẹbu si ni oun, bẹẹ lo fi kun un pe oun nikan naa ni iya oun bi.

Ọmọ ogun ọdun ni Ibrahim yii loun wa ti oun ti kuro labẹ iya oun, tiyẹn n gbe ni Ikọtun, l’Ekoo. Bẹẹ lo fidi ẹ mulẹ pe mama naa ko mọ pe oun ti ha sọwọ ọlọpaa bayii.

Ọmọ Ibo, Peter Okenu ti wọn lo ranṣe pe wọn yii naa ba ALAROYE sọrọ, alaye to ṣe ni pe oun ko mọ wọn ri, o ni irọ ni wọn pa mọ oun.

O ni ohun ti oun mọ ni pe nitori ti oun jọ ọga oun daadaa ni wọn ṣe lero pe tawọn ba parọ, boya wọn yoo jọ tu awọn silẹ ni.

Ọmọ ọdun mẹrinlelogun loun naa pera ẹ. Eyi to kere ju ninu wọn, ọmọ ọdun mejidinlogun ni, Ṣowẹmimọ Faruq lo pe orukọ ara ẹ, bakan naa lo sọ pe oun ti kabaamọ gidigidi, nitori oun ko mọ pe iṣẹ buruku ti wọn pe oun fun niyẹn ki oun too wọ wahala bayii.

Lara awọn nnkan ti wọn ba lọwọ wọn niwọnyi; Mọto Toyota Highlander kan pẹlu ibọn ibilẹ meji, ada meji, foonu Samsung kan, foonu techno tablets kan ati Samsung galaxy a-10 kan.

 

 

Leave a Reply