Faith Adebọla
Ahamọ awọn ọlọpaa tọ n gbọ ẹsun iwa ọdaran abẹle ni ẹka ti wọn ti n gbogun ti ifiyajẹni ati ṣiṣe majeṣin baṣubaṣu ni Ṣade Adelọwọ, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn, wa bayii, ibẹ ni wọn ti n bi i leere ohun to jẹ yo to fi yọ bileedi ti ọmọ alamuulegbe ẹ, Kẹhinde Ojo, ọmọọdun mọkanla, to si fibinu ya batani buruku si i lara, latari pe o lo ja oun lole.
Iṣẹlẹ buruku yii la gbọ pe o waye lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹwaa yii, lagbegbe Giwa, Oke-Aro, nipinlẹ Ogun, ibẹ ni Ṣade n gbe pẹlu awọn ọmọ rẹ meji.
Iya Kẹhinde ni wọn lo sare janna janna waa fẹjọ afurasi ọdaran naa sun ni teṣan ọlọpaa Agbado, bẹẹ lo mu ọmọ rẹ ọhun dani pẹlu ẹjẹ ṣuruṣuru to n ṣan lara rẹ, o ni kawọn ọlọpaa ba oun beere ẹṣẹ tọmọ oun ṣẹ ti wọn fi fẹẹ fi bileedi da ẹmi legbodo.
Loju-ẹsẹ ni DPO ọlọpaa ibẹ, CSP Kẹhinde Kuranga, ti paṣẹ fawọn ọmọọṣẹ, wọn tẹle obinrin naa, wọn si lọọ fi pampẹ ofin gbe Ṣade Adelọwọ.
Ni teṣan, Ṣade ni ki wọn ṣe oun jẹẹjẹ, oun o ṣadeede ya ọmọ naa ni bileedi, o lọmọ yii lo maa n duro ti oun ni gbogbo igba ti mama rẹ ko ba si nile, oun loun maa n tọju ẹ, ṣugbọn lọsan-an ọjọ naa, iyalẹnu lo jẹ foun pe ẹgbẹrun mẹta naira (N3,000) to wa ninu pọọsi oun dawati, oun si fura pe ko sẹni meji to le mu un ji oun lowo naa ju Kẹhinde yii lọ, tori oun nikan lo wa pẹlu oun lasiko naa.
O tun ṣalaye pe bi ọmọ naa ṣe taku, ti ko jẹwọ nigba toun bi i leere lo bi oun ninu toun fi fi bileedi kọ ọ lọgbọn, ṣugbọn oun o mọ pe ọgbẹ bileedi naa maa jinlẹ to bẹẹ lara ọmọ ọlọmọ ọhun.
O loun loun maa n ba iya ọmọ naa mojuto awọn ọmọ rẹ nigbakuugba tiyaa wọn ba wa jijẹ mimu wọn lọ.
Awọn ọlọpaa ni iwadii tawọn ṣe fihan pe lati bii ọdun diẹ sẹyin ni baba awọn ọmọ yii, ti meji ninu wọn jẹ ibeji ti ṣadeede sa kuro nile, ti ko si boju wẹyin, to si jẹ iya wọn nikan lo n gbọ bukaata ọmọ mẹta ti ọkunrin naa da si i laya. Eyi ni wọn lo fa a tawọn ọmọ ọhun fi dẹni tawọn aladuugbo n ba a mojuto nigba ti ko ba si nile, ọdọ afurasi ọdaran yii lo maa n fi ọmọ naa si pe ko ba oun ṣọ wọn toun maa fi de lalẹ.
Ṣa, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, ti gbọ sọrọ yii, o si ti paṣẹ pe ki wọn fun ọmọ naa ni itọju iṣegun to peye lọsibitu kan ti wọn mu un lọ, ibẹ lo wa titi di ba a ṣe n sọ yii.
Bakan naa lo ni ki iwadii to lọọrin waye lori iṣẹlẹ ọhun. O ni gbara ti iwadii ba ti pari, afurasi ọdaran yii yoo lọọ fẹnu ara ẹ sọ ohun to ri lọbẹ to fi waro ọwọ niwaju adajọ laipẹ.