Salisu fada ṣa Fulani kan ni Kwara, o lo fi maaluu jẹko oun 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni ọmọ ilẹ Togo, to jẹ ẹni ọdun marundinlaaadọta kan, Kosi Salisu, fi ada da ọgbẹ sara Fulani ọmọ dun mẹrindinlogun kan niluu Owode, nijọba ibilẹ Moro, nipinlẹ Kwara.

ALAROYE gbọ pe Umaru Abdullahi ti o jẹ Fulani lo mu ẹsun lọ sọdọ ajọ ẹsọ alaabo ilu, ṣifu difẹnṣi (NSCDC) to wa ni ilu Banni, nijọba ibilẹ Moro, pe nigba toun n da maaluu lọ, maaluu kan ṣeesi wọ inu oko ọmọ ilẹ Togo kan ti orukọ rẹ n jẹ Kosi Salisu, lo ba tori ẹ ṣa oun ladaa ni gbogbo ara.

Alukoro ẹsọ alaabo (NSCDC) ẹka ti ipinlẹ Kwara, Babawale Zaid Afọlabi, ni nigba ti awọn bẹrẹ iwadii, awọn pe Salisu ko waa wi tẹnu ẹ, o si jẹwọ pe loootọ loun ṣa a ladsa nigba to da maaluu sinu oko oun, sugbọn awọn dijọ ṣe ara awọn leṣe ni, tori pe ọgbẹ wa lara toun naa.

Ajọ naa ti ni ki Umaru to jẹ ọmọ Fulani lọọ tọju ara rẹ nileewosan, wọn si gba oniduuro Salisu naa pe koun naa lọọ tọju ara rẹ. Wọn ni iwadii yoo maa tẹsiwaju lori iṣẹlẹ naa.

 

Leave a Reply