Sanwo-Olu ṣeleri iranlọwọ fawọn ontaja Lẹkki ti wọn ba ṣọọbu wọn jẹ

Jide Alabi 

Nitori bi awọn ọmọ ita ṣe ja iwọde ti awọn ọdọ n ṣe lodi si SARS gba, ti wọn si fi asiko naa ba dukia ọpọ eeyan jẹ lo mu ki Gomina Bababjide Sanwo-Olu sabẹwo sawọn olugbe Lẹkki atawọn to n taja ni ile itaja Circle Mall ti wọn padanu ile ati awọn ọja wọn sọwọ awọn ọmọọta yii ni ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.

Lasiko abẹwo naa lo ṣeleri iranlọwọ fawọn lanlọọdu ti ile wọn jo lasiko naa atwọn to ni ṣọọbu si ile itaja nla to wa ni Lẹkki tawọn ọmọọta naa fọ, ti wọn si ko ọpọlọpọ ọja wọn lọ.

Bakan naa lo ni ijọba oun yoo ran awọn ti wọn padanu ọja wọn lọwọ, bẹẹ loun yoo tun fun awọn ontaja naa lanfaani lati ma san owo ori fungba diẹ, Bẹẹ lo rọ ijọba apapọ lati nawọ iru anfaani ọlude owo-ori yii si awọn eeyan naa.

Akọwe gomina lori eto iroyin, Gboyega Akọsile, lo sọ eleyii di mimọ ninu atẹjade kan to fi sita ni Monde, ọjọ Aje ọsẹ yii, nipa abewo gomina.

Sanwoolu ni ijọba ko ni i da awọn eeyan naa da iṣoro wọn, o ni gbogbo ọna to ba yẹ lawọn yoo fi ran wọn lọwọ ki wọn le ba a pada bo sipo.

Gomina ni awọn yoo pese owo iranwo ati eto ẹyawo fun awọn ontaja Circle Mall ti awọn janduku bajẹ ọhun. O fi kun un pe oun ti n ba awọn ileeṣẹ eto inawo sọrọ lati pese ẹyawo ti ko ni i ni ele lori fun wọn.

Awọn eeyan ile itaja naa dupẹ lọwọ gomina fun abẹwo rẹ, wọn bẹbẹ fun iranlọwọ rẹ ki wọn le bọ tete bọ sipo.

Leave a Reply