Sanwo-Olu ṣe afikun owo-oṣu awọn oṣiṣẹ LAWMA, o ni ki wọn dibo fun ẹgbẹ APC

Monisọla Saka

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, ti ṣafikun owo oṣu awọn oṣiṣẹ gbalẹ-gbadọti, atawọn awakọ to n ko ilẹ danu, titi kan awọn ti wọn n gba opopona nipinlẹ Eko, pẹlu ida ogun.

Ọga agba ajọ LAWMA, Ọgbẹni Ibrahim Ọdumboni, lo fọrọ naa lede l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Keji, ọdun 2023 yii.

Nibẹ lo ti ṣalaye pe Gomina Sanwo-Olu ti ṣeleri fawọn oṣiṣẹ LAWMA ti wọn wa labẹ akoso ẹgbẹ awọn ti wọn n gba ilu mọ lorilẹ-ede Naijiria, Association of Waste Managers of Nigeria, AWMN, pe oun yoo fi kun owo-oṣu wọn, bẹẹ lo tun rọ wọn lati dibo fun ẹgbẹ oṣelu APC ninu eto idibo to n bọ yii, ki iṣẹ rere ijọba ẹ le tẹsiwaju. Nibi ipade to ba awọn agbalẹ ṣe lolu ileeṣẹ wọn to wa lagbegbe Ijọra-Ọlọpaa, nipinlẹ Eko, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ni Ọdumboni ti sọrọ naa.

O tẹsiwaju pe Sanwo-Olu tun fawọn oṣiṣẹ naa lọkan balẹ pe oniruuru awọn ohun eelo ti yoo mu ki iṣẹ wọn rọrun, bii aṣọ toke-tilẹ alawọpọ (overall) bata ojo (boots), atawọn ohun eelo mi-in bẹẹ loun yoo pese fun wọn.

O fi kun un pe ijọba to nifẹẹ awọn oṣiṣẹ ataraalu lọkan ni ijọba to wa lori aleefa bayii, gbogbo akitiyan wọn ni wọn yoo si ṣa lati ri i daju pe wọn ṣatilẹyin to yẹ fawọn oṣiṣẹ lati le ṣiṣẹ wọn pẹlu irọrun lai si wahala.

Leave a Reply