Faith Adebọla
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, ti sin awọn ọdọ to n gbero lati ṣewọde ta ko bi ijọba ṣe fẹẹ ṣi Too-geeti Lẹkki pada ni gbẹrẹ ipakọ pe iwọde kọ lọrọ to wa nilẹ yii kan, o ni ki wọn jawọ ninu iwa to le mu ifasẹyin ba ipinlẹ Eko.
Lori atẹ ayelujara abẹyẹfo (tuita) rẹ nikilọ ọhun ti waye lọjọ Aje, Mọnde yii, latẹnu akọwe iroyin rẹ, Ọgbẹni Gbenga Akosile.
Ohun ta a gbọ ni pe latari bawọn ọdọ meji to n ṣoju fawọn ọdọ Eko ninu igbimọ oluṣewadii ẹsun ta ko iwakiwa awọn ọlọpaa SARS ṣe fariga pe awọn o fọwọ si bi igbimọ naa ṣe pinnu pe ki wọn ṣi Too-geeti naa pada, ki wọn si jẹ ki ileeṣẹ LCC to ti n ṣiṣẹ nibẹ latilẹ maa ba iṣẹ wọn lọ. Wọn lawọn ọdọ naa fẹẹ ṣe iwọde nla kan lọjọ kẹtala, oṣu keji yii, iyẹn ọjọ Abamẹta, Satide.
Lori atẹ tuita (twitter), awọn ọdọ naa kọ ọ sibẹ pe akọle iwọde awọn ni #Occupy Lekki Toll Gate, ọgọọrọ awọn to kọ ọrọ sabẹ akọle naa ni wọn lawọn nifẹẹ si ipinnu ati igbesẹ awọn ọdọ naa, wọn si lawọn maa jade lọjọ naa lati ti wọn lẹyin.
Ṣugbọn Gomina Sanwo-Olu ni kawọn ọdọ ma ṣe gbe iru igbesẹ yii, o ni ijọba oun ko ni i gba kẹnikẹni doju ipinlẹ Eko de, tabi ki yanpọnyanrin tun ṣẹlẹ nipinlẹ naa, o ni kawọn ọdọ naa ranti pe nibi ti ẹtọ tẹnikan pari si ni tẹlomi-in ti bẹrẹ, tori naa, kaluku gbọdọ bọwọ fun ẹtọ tọtun-tosi ni.
Satide to kọja yii, nibi ijokoo igbimọ oluṣewadii naa lawọn mẹrin ti ta ko ipinnu igbimọ ọhun, wọn lawọn o fara mọ bi wọn ṣe fẹẹ ṣi Too-geeti yii lai tuṣu desalẹ ikoko nipa ohun to ṣẹlẹ logunjọ, oṣu kẹwaa, ọdun 2020, ti wọn pa awọn ọdọ to n ṣewọde nibẹ, ti ọgọọrọ si fara pa loriṣiiriṣii.
Awọn mẹrin to ta ko ipinnu igbimọ naa ni Amofin agba Ẹbun-Olu Adegboruwa, Abilekọ Patience Udoh, Omidan Rinu Oduala ati Temitọpe Majẹkodunmi tawọn ṣoju fun awọn ọdọ.
Ṣugbọn alaga igbimọ naa, Adajọ-fẹyinti Doris Okwobi, Ọgbẹni Ṣẹgun Awosanya tawọn eeyan mọ si Segalink, Abilekọ Oluwatoyin Odusanya (ajafẹtọọ) Ọlọpaa-fẹyinti Taiwo Lakanu ati Ọgbẹni Lukas Koyejọ lati ajọ ijọba apapo to ri si ẹtọ ọmọniyan wa lara awọn marun-un to fọwọ si ṣiṣi too-geeti naa pada.