Faith Adebọla, Eko
Ijọba ipinlẹ Eko ti yi ipinnu rẹ lati jẹ kawọn ọmọleewe alakọọbẹrẹ ati girama lawọn ileewe to jẹ tijọba, wọle lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanlelogun, ọsu kẹsan-an yii, wọn ni kawọn kan ninu wọn ma ti i wọle na, ki wọn ṣi jokoo sile wọn.
Awọn tọrọ kan ni awọn ọmọleewe alakọọbẹrẹ atawọn to wa ni ipele ọdun kin-in-ni ati ikeji ni ileewe girama akọkọ (JSS 1&2), ati ipele kin-in-ni girama agba, (SS1), wọn ni kawọn naa ṣi fidi mọle bayii, wọn ko ti i le wọle.
Kọmiṣanna feto ẹkọ nipinlẹ Eko, Abilekọ Fọlaṣade Adefisayọ, lo sọrọ naa laaarọ ọjọ Aiku, Sannde yii, ninu atẹjade kan ti adari ẹka ọrọ to kan araalu lọfiisi naa, Kayọde Abayọmi, fi sọwọ sawọn oniroyin.
O ni kiki awọn akẹkọọ to wa nipele JS kẹta ati SS keji lawọn ileewe sẹkọndiri to jẹ tijọba ni yoo wọle lọjọ kọkanlelogun, oṣu yii.
O fikun un pe niṣe nijọba tubọ fẹẹ woye bi arun Koronafairọọsi yii ṣe n lọ silẹ si, tori oju lalakan fi n ṣọri, awọn ko si fẹ kawọn ọmọleewe rọ wọle biba leekan naa ni wọn ṣe yi eto ti wọn ti kọkọ kede rẹ pada.
Ni ti awọn ileewe aladaani, o ni awọn alakooso ileewe kọọkan lo maa pinnu boya ki gbogbo awọn akẹkọọ ileewe wọn wọle lẹẹkan naa tabi ki wọn wọle diẹdiẹ, bi wọn ba ṣe fẹ.
Kọmiṣanna naa ṣalaye pe iwọle awọn akẹkọọ to wa nipele JS3 ati SS3 yii yoo jẹ ki wọn le gbaradi fun idanwo aṣekagba Basic Education Certificate Examination, BECE, ti wọn yoo fi bọ si ipele ẹkọ mi-in.
Ni bayii, ijọba ni kawọn akẹkọọ to wa lawọn kilaasi ti ijọba ko ti i faaye gba lati wọle ṣi maa ba eto ẹkọ wọn lọ lori ikanni ayelujara ti wọn ti n lo, ati lori eto tṣlifiṣan gbogbo.
O rọ gbogbo awọn alakooso ileewe aladaani lati ri i pe wọn tẹle awọn alakalẹ tijọba paṣẹ lori idena arun Korona yii, tori awọn oṣiṣẹ ẹka eto ẹkọ yoo maa lọ lati ileewe kan si omi-in fun ayẹwo bi ileewe naa ba ṣe pa ofin ijọba mọ si.