Sanwo-Olu ni yoo ṣaaju ipolongo ibo Akeredolu l’Ondo

Bi gbogbo nnkan ba lọ bo ṣe yẹ, Satide, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii, ni  ẹgbẹ oṣelu APC yoo ṣe ifilọlẹ igbimọ ẹlẹni mọkanlelọgọrin ti wọn gbe kalẹ lati mojuto ipolongo ibo Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu.

Alaga igbimọ alaamojuto ẹgbẹ oṣelu APC, to tun jẹ gomina ipinlẹ Yobe, Mai Malla Buni, lo kede ọrọ naa. O ṣalaye pe Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ni yoo jẹ olori igbimọ ti yoo ṣe ipolongo ibo fun Gomina Akeredolu ninu ibo ti yoo waye lọjọ kẹwaa, ọṣu kẹwaa, ọdun yii.

Gomina ipinlẹ Plateau, Simon Lalong, ni yoo ṣe igbakeji Sanwo-Olu, nigba ti Komreedi Mustapha Salihu yoo ṣe akọwe.

Aago meji ọsan ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, ni ireti wa pe wọn yoo ṣe ifilọlẹ awọn ọmọ igbimọ naa niluu Abuja.

 

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Pasitọ Chibuzor fun awọn obi Deborah ni ile fulaati mẹrinla atawọn ẹbun mi-in

Monisọla Saka O da bii pe iku Deborah, ọmọbinrin ti awọn awọn kan juko pa, …

Leave a Reply

//ashoupsu.com/4/4998019
%d bloggers like this: