Sanwo-Olu paṣẹ ki wọn tu awọn tọlọpaa mu lasiko iwọde SARS silẹ

Faith Adebọla, Eko

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, ti paṣẹ pe kileeṣẹ ọlọpaa ati ẹka eto idajọ nipinlẹ naa tete tu gbogbo awọn ti wọn mu fun ẹsun kan tabi omi-in lasiko iwọde ta ko SARS to kọja laipẹ yii silẹ, ki kaluku wọn maa lọ sile rẹ lalaafia.

Amofin agba to tun jẹ kọmiṣanna feto idajọ nipinlẹ Eko, Adajọ Moyọsọrẹ Onigbanjo, ni gomina fi iṣẹ naa ran laaarọ ọjọ Aiku, Sannde yii.

O ni lara ọtalelọọọdunrun o le ẹyọ kan (361) eeyan tileeṣẹ ọlọpaa mu pe wọn rufin lasiko iwọde ọhun, ọtalerugba o din meje (253) ninu wọn ni ẹka to n gba ẹjọ araalu ro, to si n fun adajọ nimọran (Directorate for Public Prosecution), ti lọọ ṣewadii wọn, ti wọn ko si ri idi kan lati ba wọn ṣe ẹjọ, tori ko si ẹri lati fi gbe ẹsun ti wọn fi kan wọn lẹsẹ.

Latari eyi ni gomina fi paṣẹ pe ki wọn tu awọn eeyan naa silẹ nibikibi ti wọn ba fi wọn pamọ si, iba a jẹ ahamọ ọlọpaa tabi ọgba ẹwọn.

Onigbanjo sọ siwaju pe ogoji ẹsun lawọn ọlọpaa ko wa sẹka eto idajọ lọjọ kẹrin si ikarun-un, oṣu yii, eeyan to ju ọgọrun-un lọ si lọrọ ẹjọ naa kan. Loju ẹsẹ lo lawọn ti fi awọn iwe ẹsun to kan ọgọrin eeyan lara wọn ṣọwọ sawọn ile-ẹjọ loriṣiiriṣii ki igbẹjọ le tete bẹrẹ lori wọn, awọn si da iwe ẹṣẹ eeyan mẹrindinlogun pada sọdọ awọn ọlọpaa fun iwadii lori ẹsun ti wọn fi kan wọn bii fifọ ile onile, biba dukia ẹlomi-in jẹ, ole jija, didana sun dukia ijọba, iṣikapaniyan ati dida omi alaafia ilu ru.

Onigbanjo ni lati ọjọ Aje, Mọnde yii, ni igbẹjọ yoo bẹrẹ lori wọn.

Leave a Reply