Faith Adebọla, Eko
Ijọba ipinlẹ Eko ti kede pe meji lara awọn ibi igbafẹ ti wọn ti ti pa fun bii oṣu marun-un sẹyin yoo di ṣiṣi bayii fawọn to ba fẹẹ gbafẹ tabi ṣere idaraya nibẹ, bẹrẹ lati ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.
Atẹjade kan to tẹ ALAROYE lọwọ latọdọ igbakeji ọga agba ni ọfiisi ọrọ to kan araalu (Public Affiars) ti ẹka LASPARK, Abilekọ Titilayọ Ajirọtutu, sọ nirọlẹ ọjọ Aiku, Sannde, to kọja yii pe Gomina Babajide Sanwo-Olu lo paṣẹ ṣiṣi awọn ibi igbafẹ naa, kawọn eeyan le lanfaani lati bẹrẹ si i lo ibẹ.
Awọn ibi igbafẹ meji ọhun ni Ndubuisi Kanu Park, to wa ni Alausa, Ikẹja, ati Dr. Abayọmi Finnish Park to wa lagbegbe Ọrẹgun, n’Ikẹja kan naa.
Atẹjade naa ni ijọba Eko mọ bi titi awọn ibi igbafẹ wọnyi pa ṣe ri lara awọn ti wọn maa n waa gbatẹgun nibẹ, ti wọn maa n daraya, tawọn ọmọde naa si maa n gbadun ara wọn lọpọ igba pẹlu awọn obi tabi olukọ wọn, ati pe owo tijọba n pa wọle lawọn ibi igbafẹ ọhun ko wọle mọ lasiko konilegbele.
O ni, ni kẹrẹkẹrẹ, awọn ibi igbafẹ ati papa idaraya yooku maa di ṣiṣi bijọba ṣe n ri i pe a ti n kapa arun aṣekupani Korona lọ.
Amọ ṣa, ọrọ ikilọ fawọn to ba fẹẹ lọ sibi igbafẹ naa ni pe, lasiko yii, ko saaye fẹnikẹni tọjọ ori ẹ ba ti kọja ọdun marundinlọgọrin (65).
Awọn ti ko si ti i pe ẹni ọdun marundinlaaadọrin to fẹẹ waa gbafẹ lawọn ibi igbafẹ naa gbọdọ pa ofin ati alakalẹ arun Korona mọ, bii lilo ibomu tabi iboju wọn, fifọwọ pẹlu omi ati ọsẹ lawọn ibi ifọwọ ti wọn ti pese sibẹ, wọn si gbọdọ yọnda ki wọn fi ẹrọ ṣayẹwo bi ara wọn ṣe gbona si nigba ti wọn ba fẹẹ wọle.
Koko pataki mi-in ninu atẹjade naa ni pe wọn ko ni i yọnda ki ero to maa wa nibi igbafẹ ti Ọrẹgun ju aadọjọ (150) eeyan lọ, ti Alausa ko si ni i gba ju ọgọrun-un (100) eeyan lọ lasiko yii na.