Ibrahim Alagunmu Ilọrin,
Ajọ ẹsọ alaabo ẹni laabo ilu, (NSCDC), ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti mu awọn Fulani ti ko din ni ọgọrun-un kan ti wọn ya wọ ilu Bode Saadu, nijọba ibilẹ Moro, nipinlẹ Kwara.
Agbẹnusọ ajọ ẹṣọ alaabo ọhun, Babawale Zaid Afọlabi, lo fidi iṣẹlẹ naa mulẹ niluu Ilọrin. O ni ikọ awọn ti mu awọn Fulani to ya wọ Bode Saadu, nijọba ibilẹ Moro, nipinlẹ Kwara, o salaye pe lasiko ti ikọ awọn n yide kiri niluu naa lawọn kofiri awọn Fulani to jẹ ajoji ọhun nibi ti wọn ti n kirun, lai mọ ibi ti wọn ti wa.
O tẹsiwaju pe, nigba ti wọn kirun tan ni ọwọ tẹ wọn, nigba ti wọn fi ọrọ wa wọn lẹnu wo ni awọn ri i pe wọn fẹẹ tẹdo sibẹ, ti wọn yoo si fi ilu naa ṣe ibugbe ni, eyi lo mu ki awọn fa wọn le awọn alaṣẹ to yẹ lọwọ lati wadii ibi ti wọn ti wa.
Ọga agba ajọ ẹṣọ alaabo ọhun, ẹka ipinlẹ Kwara, Iskil Ayinla Makinde, ti waa rọ gbogbo olugbe ipinlẹ Kwara lati tete maa ta awọn ẹsọ alaabo lolobo ti wọn ba kẹẹfin awọn oju tuntun ni agbegbe wọn tori pe ijafara lewu.