Monisọla Saka
Awọn ọmọ Naijiria ti n pe fun idajọ ododo lori mọlẹbi kan ti wọn fẹẹ fọwọ ọla gba loju, latari bi wọn ṣe n ja fun ọmọ wọn obinrin, ọmọ ọdun mẹrin, ti aṣọgba ileewe wọn fipa ba lajọṣepọ ninu ọgba ileewe wọn ọhun, Greater Scholars International School, eyi to wa ni agbegbe Lekki.
Nigba ti oludasilẹ ileewe naa ko ṣe nnkan kan lori ọrọ ọhun ni baba ọmọ ọhun gba teṣan ọlọpaa lọ lati fẹjọ sun, ṣugbọn niṣe ni obinrin to nileewe naa tun dẹ awọn janduku si i lati lu u ti ko ba dẹyin ẹsun to fi n kan aṣọgba naa.
Oriṣiiriṣii awọn eeyan lori ẹrọ ayelujara ni wọn ti n pe ileeṣẹ ọlọpaa, paapaa ju lọ, agbẹnusọ wọn nipinlẹ Eko, Benjamin Hundenyin, lati da sọrọ naa.
Ọkunrin kan to n jẹ Ọmọlọmọ lori ẹrọ abẹyẹfo Twitter, ke si alukooro ọlọpaa ipinlẹ Eko, pe ki wọn ma ṣe jẹ ki iya jẹ ọmọ kekere naa atawọn obi ẹ gbe.
O ni, “Greater Scholar lorukọ ileewe ọhun, wọn si ti n fi owo di awọn ọlọpaa lẹnu. Ọkunrin getimaanu yii tun wa n leri leka pe oun maa bọ ninu ọrọ yii lai si wahala kankan, o ni ko si nnkan ti wọn le fi oun ṣe, nitori oun mọ bi ileewe naa ṣe lagbara to, agaga lori ọrọ ọlọpaa de. Ohun to waa buru ju nibẹ ni pe ẹrin ni ọkunrin getimaanu ọhun n rin nigba ti baba ọmọ naa waa fẹjọ sun nileewe wọn. Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Eko, Ben Hundenyin, a n fẹ idajọ ododo o”.
Nigba to n ṣalaye iha tawọn ọga ileewe ati iya to da ileewe naa silẹ kọ si ẹsun naa, o ni, “Nigba tọkunrin ọdẹ ileewe wọn yii ṣe aṣemaṣe pẹlu ọmọdebinrin naa tan, ọdọ olukọ wọn lọmọ yii gba lọ taara, pe Ọgbẹni David fi kinni rẹ sinu idi oun, ṣugbọn dipo ki wọn ṣe oun to tọ, niṣe ni ọga naa yọ ẹgba, to fin ọmọ yii latoke delẹ, lẹyin naa lo sọ fun un pe ko gbọdọ wi fẹnikẹni”.
O ni Comfort Ukpong, lorukọ iya to nileewe ọhun. Wọn ni obinrin naa ti fawọn ọlọpaa teṣan Ajiwe, agbegbe Lekki, nipinlẹ Eko, lowo, awọn yẹn si ti dẹ awọn gidigannku si baba ọmọ naa, pe ko so ewe agbejẹ mọwọ, ko ma si ṣe pẹ̀ẹ̀kẹ́ lu ọrọ naa mọ, ti ko ba fẹẹ kan idin ninu iyọ.
Ẹni kan toun naa tun sọrọ lori iṣẹlẹ yii sọ pe, awọn alaṣẹ ileewe naa ti din iye eeyan to le kọ ariwisi sori ikanni ayelujara wọn ku.
O ni nigba ti wọn gbe bebi olowuu fọmọ naa lati ṣapejuwe nnkan ti wọn ṣe fun un, bọrọ ṣe ri gẹlẹ lo ṣe ṣafihan rẹ, ṣugbọn niṣe ni wọn deru ba a pe ko ma sọ fẹnikankan.
Wọn lawọn alaṣẹ ileewe ko jẹ kawọn ọlọpaa ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ, tọọgi ni wọn si fi le wọn jade nigba ti wọn fẹẹ fẹjọ sun.
Wọn waa ke sawọn ọmọ Naijiria, agaga awọn ti wọn wa lori ẹrọ ayelujara kaakiri, lati maa fọnrere ọrọ naa, ko fi le de etiigbọ awọn alaṣẹ tọrọ kan.
Bẹẹ ni wọn tun rọ Benjamin Hundenyin, ti i ṣe alukoro ọlọpaa Eko, lati gbe igbesẹ to yẹ lori ọrọ naa ni kiakia.
Ibrahim Alagunmu, Ilọrin