Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Awọn ọlọpaa ti fi pampẹ ofin gbe ọkunrin ẹni ọdun mejidinlọgbọn kan, Sunday Udoh, lori ẹsun gbigbiyanju ati sẹyun fun ọmọ to bi ninu ara rẹ to fun loyun.
ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayọ Ọdunlami, pe ọwọ tẹ Udoh lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii nileewosan alabọọde kan to mu ọmọninrin ti ko tii ju bii ọmọ ọdun mẹẹdogun ọhun lọ lati sẹyun fun un.
Ọdunlami ni afurasi ọhun funra rẹ jẹwọ lasiko tawọn n fọrọ wa a lẹnu wo pe aimọye igba loun ti ba ọmọ oun ni ajọṣepọ kọrọ naa too pada yọri si oyun.
O ni awọn ti fi ọdaran naa fi ṣọwọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n mojuto ọrọ to ba jẹ mọ iru iṣẹlẹ yii fun ẹkunrẹrẹ iwadii.