Awọn agbẹjọro lati orileede Olominira Benin, Naijiria, France ati ilẹ Gẹẹsi lo wa lori ọrọ ọkunrin ajafẹtọọ ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Igboho, ti wọn n ja fitafita lati ri i pe wọn ko gbe ọkunrin naa pada si Naijiria. Alaga gbogboo fun agbarijọpọ ẹgbẹ Ilana Oodua, Ọjọgbọ Wale Adeniran, lo sọ eleyii nibi ipade ori ẹrọ ayelujara to ṣe pẹlu awọn ọmọ Yoruba kaakiri agbaye, eyi ti Tẹlifiṣan Heritage ṣe agbatẹru rẹ.
Baba naa ṣalaye pe ko si ootọ ninu ahesọ ti awọn eeyan n gbe kiri pe ọkunrin ti wọn n pe ni Igboho Ooṣa yii ti kuro ni Cotonou, lọ si orileede mi-in. O ni o ṣi wa nibẹ, bo tile jẹ pe wọn ko jẹ ki awọn agbẹjọro ri i.
Adeniran ni ‘’Mo ti ba agbẹjọro rẹ sọrọ, agbẹjọro rẹ si ti ṣabẹwo sibi ti wọn sọ pe o wa, ṣugbọn wọn ko jẹ ko ri i, bo tilẹ jẹ pe wọn fidi ẹ mulẹ pe loootọ lo wa nibi ti wọn mu un pamọ si yii. Aago mẹjọ aarọ ọjọ Wẹsidee, ti i ṣe ọjọ kọkanlelogun, o ṣu yii, ni wọn ni ko pada wa.
‘’Mo waa beere pe ṣe wọn ko ni i lo ọgbọn arekereke pe ki wọn waa yọ mu un pada wa si Naijiria, agbẹjọro naa sọ pe ko le ṣeeṣe.
‘’Lati ọsẹ to kọja la ti beere fun iwe aṣẹ ifaaye gba ẹni to sa niluu ẹ nitori wahala kan fun idaabo bo rẹ, eyi ti oloyinbo n pe ni (asylum), fun un, emi gan-an ni mo mojuto gbogbo eleyii pẹlu awọn agbẹjọro to n ri si iwọle-wọde, wọn si fọkan mi balẹ pe niwọn igba ti a ti beere fun aṣẹ idaabobo yii, wọn ko lee gbe e wa si Naijiria.
Ireti wa pe awọn agbẹjọro Sunday Igboho yoo ri i lonii, eto yoo si bẹrẹ lori igbesẹ fun ominira rẹ.