Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọkan lara awọn aṣaaju iran Yoruba, Dokita Yẹmi Farounbi, ti sọ pe pẹlu bi ijọba orileede Naijiria ṣe lọọ gbe Oloye Sunday Igboho niluu Kutọnu ko lodi sofin, ṣugbọn iran Yoruba ni ki wọn jokoo lati tun ero wọn pa lori ijijagbara fun ominira ti wọn n fẹ. Bayii lo ṣe lọ:
ALAROYE: Ṣe o lẹtọọ bi wọn ṣe lọọ fi pampẹ ofin mu Sunday Igboho lorileede Benin Republic?
Dokita Farounbi: Ti wọn ba ti kede pe wọn n wa eeyan, ibikibi ni wọn ti le fi pampẹ ọba gbe e, awọn ọlọpaa agbaye (Interpol) le mu un nibikibi, niwọn igba ti ifọwọsowọpọ pẹlu awọn ọlọpaa agbaye ba ti wa, wọn le mu un.
ALAROYE: Ṣe ko wAa lewu ki wọn gbe e wa si orileede Naijiria lati jẹjọ?
Dokita Farounbi: Niwọn igba ti wọn ti mu un, ko si ọrọ kankan mọ nibẹ, wọn aa mu un wa si orileede Naijiria, ohun ti ofin sọ niyẹn. Idi ni pe ko ni ẹjọ kankan pẹlu ijọba orileede Benin Republic, wọn kan fi pampẹ ofin mu un latari ikede ti awọn ọlọpaa agbaye fi sita nipa rẹ ni, niwọn igba ti Naijiria si wa lara awọn orileede ti awọn ọlọpaa agbaye ti n ṣiṣẹ, wọn lagbara lati mu un.
ALAROYE: Ṣe nnkan ti wọn ṣe yii ko ni i da omi tutu sọkan awọn ajijagbara ilẹ Yoruba?
Dokita Farounbi: Lero temi, ijijagbara Yoruba ko bẹrẹ lati ọdọ Sunday Igboho, oun kọ lo bẹrẹ rẹ, ijijagbara pe ki Yoruba da duro, o ti bẹrẹ latigba ti wọn ti n beere fun ijokOo gbogbo ẹya ati ajọ ni gbogbo Naijiria (Sovereign National Conference) lọdun 1992, lara awọn ti wọn jọ bẹrẹ ijijagbara yii ni MKO Abiọla, ẹ ri i i pe ọdun naa ti pẹ, niwọn igba ti ọrọ naa ko si ti i loju, iyẹn lo ṣe n tẹ siwaju.
Inu Yoruba ko dun rara, ti wọn ba fẹ ki ijijagbara dopin, ijọba gbọdọ mu inu wọn dun, ki wọn jẹ ki gbogbo nnkan rọ wọn lọrun, nigba yẹn ni ijijagbara le dopin, lai ṣe eleyii, oniruuru eeyan a maa dide loorekoore lori rẹ ni, bo ṣe jẹ niyẹn.
ALAROYE: Ki ni imọran fun Sunday Igboho?
Dokita Farounbi: Mi o ni i sọ imọran ti mo fẹẹ fun un sinu iwe iroyin.
ALAROYE: Ki ni imọran fun Ijọba Naijiria?
Dokita Farounbi: Imọran mi funjọba ni pe o rọrun fun wọn lati yanju gbogbo iṣoro ti orileede yii n dojukọ lọwọ bayii. Ti eeyan ba ni eewo (boils) lara, o maa ni nnkan to fa a, wọn aa lọ sọdọ dokita lati mọ nnkan to le mu eewo yẹn kuro. Nnkan to yẹ kijọba ṣe ni pe ki wọn jokoo lati mọ nnkan to fa awuyewuye, ọkan lara rẹ ni eto-aabo, ko si aabo fun wọn ninu oko, ko si aabo fun wọn ninu ile, iku n waa ba wọn loko, iku n waa ba wọn ninu ile, o buru debii pe awọn oniwahala yii lagbara lati ja baalu wa lulẹ latoke.
Ko si ilu ti ọkan eeyan yoo ti balẹ ti awọn eeyan o ni i maa ronu pe boya tawọn ba gbe e gba ọna mi-in, nnkan yoo yatọ. Ijọba ni lati wo ọrọ-aje wa, ki wọn mọ iye ounjẹ lọja, ati pe ṣawọn araalu lowo lati ra a, tijọba ba ranti pe ojuṣe wọn ni lati mu ọkan awọn araalu balẹ, wọn aa ri i pe gbogbo eewo yii maa gbẹ patapata.
ALAROYE: Ki waa ni imọran yin fun awọn ọmọ Yoruba?
Dokita Farounbi: Nnkan temi maa sọ fun awọn ọmọ Yoruba ni pe ọna to wọ ọja pọ, awọn ni wọn maa jokoo lati wo ọna to rọrun, to si ya wọn, ti ko lewu lati gba de ọja, ki wọn si maa ranti pe gbogbo Yoruba ki i sun ki wọn kọri sibikan naa.