Sunday Igboho yoo fara han nile-ẹjọ lorileede Benin

Faith Adebọla

Bi gbogbo nnkan ba lọ bi wọn ti ṣeto rẹ, aarọ Ọjọbọ, Tọsidee yii ni ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Sunday Adeyẹmọ tiu gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho yoo fara han nile-ẹjọ kan, Judicial Service Benin, to wa ni Rue 447, Cotonou, Benin 02BP2004 ni orileede Benin. Bo tilẹ jẹ pe Ọjọruu, Wẹsidee, lo ti yẹ ki igbẹjọ naa waye, ALAROYE gbọ pe iwọde ti awọn ọmọ Yoruba to wa lorileede Benin ṣe da igbẹjọ naa duro, eyi to mu ki wọn sọ ọ di oni, Tọsidee, Ọjọbọ.

Agbẹnusọ Igboho, Koiki Ọlayẹmi, fidi eyi mulẹ ninu fidio kan to ṣe lati fi ṣalaye bi nnkan ṣe n lọ ni orileede Olominira Benin ti Sunday Igboho wa bayii.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni wọn mu ajijagbara ọmọ Yoruba naa ni orileede Benin, nigba to fẹẹ maa rin irinajo ọ si ilu oyinbo

Latigba naa ni ijọba Naijiria ti n wa gbogbo ọna lati gbe ọkunrin naa wa si Naijiria lati waa jẹjọ. ALAROYE gbọ pe gbogbo agbara ni ọga ṣoja ilẹ wa tẹlẹ to ti di aṣoju ilẹ wa lorileede Benin bayii, Turkur Buratai, n ṣa lati ri i pe wọn gbe Sunday Igboho wa si Naijiria. Sugbọn awọn alaṣẹ ilẹ Benin ni awọn ko le fi ọkunrin naa silẹ ni yajoyajo bẹẹ, afi ti wọn ba tẹle gbogbo alakalẹ, ti wọn si ṣe ohun gbogbo lọna ofin. Bẹẹ ni awọn agbẹjọro ọmọ Yoruba to ti pe jọ kaakiri agbaye n ja fitafita lati ri i pe ọkunrin naa mori bọ.

Ile-ẹjọ kan, Judicial Service Benin, to wa ni Rue 447, Cotonou, Benin 02BP2004 ni ireti wa pe igbẹjọ naa yoo ti waye lonii ti i ṣe Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

Leave a Reply